13 Àwa ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run ní gbogbo ìgbà nítorí pé, ẹ kò ka ọ̀rọ̀ ìwàásù wa sí ọ̀rọ̀ ti ara wa. Pẹ̀lú ayọ̀ ni ẹ gba ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tí a wí gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, òtítọ́ sì ni pé, ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni, èyí tí ó ń ṣiṣẹ́ nínú ẹ̀yin tí ó gbàgbọ́.
14 Nítorí, ẹ̀yin ara, ẹ jẹ́ àwòkọ́se àwọn ìjọ tí o wà ní Jùdíà jẹ. Bí a ti gbógun tì wọ́n, láti ọwọ́ àwọn ará ìlú wọn (àwọn Júù), bẹ́ẹ̀ ni a gbógun ti ẹ̀yin pàápàá láti ọ̀dọ̀ àwọn Júù,
15 àwọn tí wọ́n pa Jésù Olúwa àti àwọn wòlíì, tí wọ́n sì tì wa jáde. Wọn kò ṣe èyí tí ó wu Ọlọ́run, wọ́n sì ṣe lòdì sí gbogbo ènìyàn
16 nínú ìgbìyànjú wọn láti dá ìwàásù ìyìnrere dúró láàrin àwọn aláìkọlà kí wọn kí ó lè rí gbàlà. Ẹ̀sẹ̀ wọn ń di púpọ̀ síi lójoojúmọ́. Ṣùgbọ́n ní ìkẹyìn, ìbínú Ọlọ́run ti wá sórí wọn ní ìgbẹ̀yìn.
17 Ẹ̀yin ará olùfẹ́, lẹ́yìn ìgbà tí a ti kúrò lọ́dọ̀ yín fún ìgbà díẹ̀ (nínú ara, kì í ṣe ọkàn), pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìtara ni àwa ṣe àníyàn tí a sì fẹ́ gidigidi láti fi rí i yín.
18 Nítorí àwa fẹ́ wá sí ọ̀dọ̀ yín—àní èmi, Pọ́ọ̀lù, gbìyànjú ní ọ̀pọ̀ ìgbà láti wá, ṣùgbọ́n Èṣù ú dè wá lọ́nà.
19 Kí ni ìrètí wa, ayọ̀ wa, tàbí adé wa nínú èyí tí a ó sògo níwájú Jésù Olúwa nígbà tí òun bá dé? Ṣé ẹ̀yin kọ ní?