1 Tẹsalóníkà 3:1-7 BMY

1 Nítorí ìdí èyí, nígbà tí ara mi kò gbà á mọ́, mo pinnu láti nìkan dúró ní ìlú Átẹ́nì.

2 Mo sì rán Tímótíù, arákùnrin àti alábáṣiṣẹ́ pọ̀ wá, láti bẹ̀ yín wò. Mo rán an láti fún ìgbàgbọ́ yín lágbára àti láti mú yín lọ́kà le; àti kí ó má sì ṣe jẹ́ kí ọkàn yín dàrú, nínú ìṣòro tí ẹ ń là kọjá.

3 Láìsí àníàní, ẹ mọ̀ gbangba pé, irú ìṣòro báwọ̀nyí wà nínú ètò Ọlọ́run fún àwa Kírísítẹ́nì.

4 Tó bẹ́ẹ̀ tí a fi kìlọ̀ fún yín pé ìjìyà inúnibíni yóò de. Ó sì rí bẹ́ẹ̀ nítòótọ́.

5 Bí mo wí tẹ́lẹ̀, nígbà tí ara mi kò gba ìdákẹ́jẹ́ẹ́ náà, mo rán Tímótíù láti bẹ̀ yín wò, kí ó lè mọ̀ bóyá ìgbàgbọ́ yín sì dúró gbọn-ingbọn-in. Mo funra sí i wí pé, sàtánì ti ṣẹ́gun yín. Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, iṣẹ́ wa (láàrin yín) jásí aṣán.

6 Nísìnsinyìí, Tímótíù ti dé pẹ̀lú ìròyìn ayọ̀ wí pé, ìgbàgbọ́ àti ìfẹ́ yín sì lágbára bí i ti àtẹ̀yìnwá. Inú wa dùn láti gbọ́ wí pé ẹ sì ń rántí ìbágbé wa láàrin yín pẹ̀lú ayọ̀. Tímótíù tún fi yé wa pé bí ó ti mú wa lọ́kàn tó láti rí i yín, ni ó ṣe ẹ̀yin pàápàá.

7 Nítorí náà, ẹ̀yin ará, inú wá dùn jọjọ nínú gbogbo ìyọnu àti ìjìyà wa níbí nítorí pé àwa mọ̀ nísinsinyìí pé, ẹ̀yin sì dúró gbọn-ingbọn-in fún Olúwa.