6 Kí ó má jẹ́ ẹni titun ti ó ṣẹ̀ṣẹ̀ gbàgbọ́, kí ó má baà gbéraga, a sì ṣubú sínú ẹ̀bi Èsù.
7 Ó sì yẹ kí ó ni ẹ̀rí rere pẹ̀lú lọ́dọ̀ àwọn tí ń bẹ lóde; kí ó má baà bọ́ sínú ẹ̀gàn àti sínú ìdẹ́kun Èṣù.
8 Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni ó yẹ fún àwọn Díákónì láti ní ìwà àgbà, kí wọ́n máa jẹ́ ẹlẹ́nu méjì, kí wọ́n máa fi ara wọn fún wáìnì púpọ̀, kí wọ́n má jẹ́ olójúkòkòrò.
9 Kí wọn máa di ohun ìjìnlẹ̀ ìgbàgbọ́ mú pẹ̀lú ọkàn funfun.
10 Kí a kọ́kọ̀ wádìí àwọn wọ̀nyí dájú pẹ̀lú; nígbà náà ni kí a jẹ́ kí wọn ó ṣiṣẹ́ díákónì, bí wọn bá jẹ́ aláìlẹ́gàn.
11 Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni ó yẹ fún àwọn obìnrin láti ni ìwá àgbà, kí wọn má jẹ́ asọ̀rọ̀-ẹni-lẹ́yìn bí kò ṣe aláìrékọjá, olóòótọ́ ní ohun gbogbo.
12 Kí àwọn díákónì jẹ́ ọkọ obìnrin kan, kí wọn káwọ́ àwọn ọmọ àti ilé ara wọn dáradára.