2 Kọ́ríńtì 1:9-15 BMY

9 Nítòótọ́, nínú ọkàn wa a tilẹ̀ ní ìmọ̀lára wí pé a tí gba ìdálẹ́bi ikú, ṣùgbọ́n èyí farahàn láti má mú wa gbẹ́kẹ̀lé ara wa bí kò ṣe Ọlọ́run tí ń jí òkú dìde:

10 Ẹni tí ó gbà wá kúrò nínú irú ikú tí ó tóbi bẹ́ẹ̀, yóò sí tún gbà wá; òun ní àwa gbẹ́kẹ̀ wa lé pé yóò sí máa gbà wá ṣíbẹ̀ṣíbẹ̀,

11 Bí ẹ̀yin pẹ̀lú ti ń fí àdúrà yín ìràn wá lọ́wọ́. Àti pé ọ̀pọ̀ ènìyàn ni yóò dúpẹ́ nítorí wa fún oore-ọ̀fẹ́ ojúrere táa rí gbà nípa ìdáhún sí àdúrà ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn.

12 Nítorí èyí ní ìsògo wá, ẹ̀rí láti inú ọkàn wa pẹ̀lú ìń jérìí wí pé àwa ń gbé ìgbésí ayé tí ó ní tumọ̀ pàápàá jùlọ nínú ìbágbépọ̀ wa pẹ̀lú yín, nínú ìwà mímọ́ àti òtítọ́ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá. Kì í ṣe nípa ọgbọ́n ènìyàn ni àwa ń ṣe èyí bí kò ṣe nípa oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run.

13 Nítorí pé àwa kò kọ̀wé ohun tí èyín kò lè kà mòye rẹ̀ sí yín. Mo sì tún ní ìrètí wí pé.

14 Gẹ́gẹ́ bí ẹyín pẹ̀lú ti ní ìmọ̀ nípa wa ní apákan, bákan náà ni ẹ ó ní ìmọ̀ lẹ́kùnrẹ́rẹ́ tí ẹ ó sì fi wá yangàn, bí àwa pẹ̀lú yóò ṣe fi yín yangàn ní ọjọ́ Jésù Olúwa.

15 Nítorí mo ní ìdánilójú yìí wí pé, mo pinnun láti kọ́kọ́ bẹ̀ yín wò kí ẹ lè jànfààní ìgbà méjì.