1 Gẹ́gẹ́ bí alábáṣiṣẹ́ pọ̀ nínú Ọlọ́run, ǹjẹ́, àwa ń rọ̀ yín kí ẹ má ṣe gba oore ọ̀fẹ́ Ọlọ́run lásán.
2 Nítorí o wí pé,“Ní àkókò ìtẹ́wọ́gbà mi, èmi tí gbọ́ ohùn rẹ,àti ọjọ́ ìgbàlà, èmi sì ti ràn ọ́ lọ́wọ́.”Èmi wí fún ọ, nísínsín yìí ní àkókò ìtẹ́wọ́gbà, nísínsín yìí ní ni ọjọ́ ìgbàlà.
3 Àwa kò sì gbé ohun ìkọ̀sẹ̀ kankan si ọ̀nà ẹnikẹ́ni, ki iṣẹ́ ìránṣẹ́ wa má ṣe di ìsọ̀rọ̀ òdì sí.
4 Ṣùgbọ́n dípò bẹ́ẹ̀, ni ọnà gbogbo, àwa ń fí ara wa hàn bí àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ sùúrù, nínú ìpọ́njú, nínú àìní, nínú wàhálà,
5 nípa nínà, nínú túbú, nínú ìrúkèrúdò, nínú iṣẹ́ àṣekára, nínú àìṣan, nínú ìgbààwẹ̀.
6 Nínú ìwà mímọ̀, nínú ìmọ̀, nínú ìpamọ́ra, nínú ìṣeun, nínú Ẹ̀mi Mímọ̀, nínú ìfẹ́ àìṣẹ̀tàn.
7 Nínú ọ̀rọ̀ òtítọ́, nínú agbára Ọlọ́run, nínú ìhámọ́ra òdodo ní apá ọ̀tún àti ní apa òsì.
8 Nípa ọlá àti ẹ̀gàn, nípa ìyìn búburú àti ìyìn rere: bí ẹlẹ́tàn, ṣùgbọ́n a já sí ólóòótọ́,
9 bí ẹni tí a kò mọ̀, ṣùgbọ́n a mọ̀ wá dájúdájú; bí ẹni tí ń kú lọ, ṣùgbọ́n a si wà láàyè; bí ẹni tí a nà, ṣùgbọ́n a kò sì pa wá,
10 bí ẹni tí ó kún fún ìbànújẹ́, ṣùgbọ́n àwa ń yọ̀ nígbà gbogbo; bí talákà, ṣùgbọ́n àwa ń sọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ dí ọlọ́rọ̀; bí ẹni tí kò ní nǹkan, ṣùgbọ́n àwa ni ohun gbogbo.
11 Ẹ̀yin ará Kọ́ríńtì, a ti bá yín sọ òtítọ́ ọ̀rọ̀, a ṣí ọkàn wa payá sí yín.
12 A kò ni yín lára nítorí wa, ṣùgbọ́n a ni yín lára nítorí ìfẹ́ ọkàn ẹ̀yin fúnra yín.
13 Ní sísán padà, ní ọ̀nà tí ó dára, (èmi ń sọ bí ẹni pé fún àwọn ọmọdé) ẹ̀yin náà, ẹ ṣí ọkàn yín payá pẹ̀lú.
14 Ẹ má ṣe fí àìdọ́gba dàpọ̀ pẹ̀lú àwọn aláìgbàgbọ́: nítorí idápọ̀ kín ni òdodo ní pẹ̀lú àìṣòdodo? Ìdápọ̀ kín ni ìmọ́lẹ̀ sì ní pẹ̀lú òkùnkùn?
15 Ìrẹ́pọ̀ kín ni Kírísítì ní pẹ̀lú Bélíàlì? Tàbí ìpín wó ni ẹni tí ó gbàgbọ́ ní pẹ̀lú aláìgbàgbọ́?
16 Ìrẹ́pọ̀ kín ni tẹ́ḿpìlì Ọlọ́run ní pẹ̀lú òrìṣà? Nítorí ẹ̀yin ní tẹ́ḿpìlì Ọlọ́run alààyè; gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ti wí pé, “Èmi á gbé inú wọn, èmi o sì máa rìn láàárin wọn; èmi ó sì jẹ́ Ọlọ́run wọn, wọn yóò sì jẹ́ ènìyàn mi.”
17 “Nítorí náà ẹ jáde kúrò láàárin wọn,kí ẹ sì yá ara yín si ọ̀tọ̀,ni Olúwa wí.Ki ẹ má ṣe fi ọwọ kan ohun àìmọ́;Èmi ó sì gbà yín.”
18 “Èmi o sì jẹ́ Baba fún yín,Ẹ̀yin ó sì jẹ́ ọmọkùnrin mi àti ọmọbìnrin mi!ní Olúwa Olódùmarè wí.”