2 Kọ́ríńtì 5 BMY

Ibùgbé Wa Ọ̀run

1 Nítorí àwa mọ̀ pé, bi ilé àgọ́ wa ti ayé ba wó, àwa ní ilé kan láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, ilé tí a kò fi ọwọ́ kọ́, ti ayérayé nínú àwọn ọ̀run.

2 Nítorí nítòótọ́ àwa ń kérora nínú èyí, àwa sì ń fẹ́ gidigidi láti fi ilé wa ti ọ̀run wọ̀ wá.

3 Bí ó bá ṣe pé a ti fi wọ̀ wá, a kì yóò bá wa ní ìhòòhò.

4 Nítorí àwa tí ń bẹ nínú àgọ́ yìí ń kérora nítòótọ́, kì í ṣe nítorí tí àwa yóò jẹ́ aláìwọsọ, ṣùgbọ́n pé a ó wọ̀ wá ní aṣọ sí i, kí ìyè baà lè gbé ara kíkú mì.

5 Ǹjẹ́ ẹni tí ó ti pèṣè wa fún nǹkan yìí ni Ọlọ́run, ẹni tí o sì ti fi Ẹ̀mí fún wa pẹ̀lú ni ẹ̀rí ìdánilójú ohun tí ń bọ̀.

6 Nítorí náà àwa ní ìgboyà nígbà gbogbo, àwa sì mọ̀ pé, nígbà tí àwa ń bẹ ní ilé nínú ara, àwa kò sí lọ́dọ̀ Olúwa.

7 Àwa ń gbé nípa ìgbàgbọ́, kì í ṣe nípa rírí.

8 Mo ní, àwa ní ìgboyà, àwa sì ń fẹ́ kí a kúkú ti inú ara kúrò, kí a sì lè wà ní ilé lọ́dọ̀ Olúwa.

9 Nítorí náà àwa ń dù ú, pé, bí àwa bá wà ní ilé tàbí bí a kò sí, kí àwa lè jẹ́ ẹni ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ rẹ̀.

10 Nítorí pé gbogbo wa ni ó gbọ́dọ̀ fí ara hán níwájú ìtẹ́ ìdájọ́ Kírísítì; kí olúkúlùkù lè gbà èyí tí ó ṣe gẹ́gẹ́ bí èyí tí ó tọ́ sí i ti ṣe nígbà tí ó wà nínú ara ìbáà ṣe rere tàbí búburú.

Iṣẹ́-Ìránṣẹ́ Ìlàjà Tí A Yà Sọ́tọ̀.

11 Nítorí náà bí àwa ti mọ ẹ̀rù Olúwa, àwa ń yí ènìyàn lọ́kàn padà; ṣùgbọ́n a ń fí wá hàn fún Ọlọ́run; mo sì gbàgbọ́ pé, a sì ti fì wá hán ní ọkàn yín pẹ̀lú.

12 Nítorí àwa kò sì ní máa tún yin ara wá sí i yín mọ́, ṣùgbọ́n àwa fi ààyè fún yín láti máa ṣògo nítorí wa, kí ẹ lè ní ohun tí ẹ̀yin yóò fi dá wọn lóhùn, àwọn ti ń ṣògo lodé ara kì í ṣe ní ọkàn.

13 Nítorí náà bí àwa bá ń sínwín, fún Ọlọ́run ni: tàbí bí iyè wá bá sí pépé, fún yín ni.

14 Nítorí ifẹ́ Kírísítì ń rọ̀ wá, nítorí àwa mọ̀ báyìí pé, bí ẹnìkan bá kú fún gbogbo ènìyàn, ǹjẹ́ nígbà náà, gbogbo wọ́n ni ó ti kú.

15 Ó sì ti kú fún gbogbo wọn, pé kí àwọn tí ó wà láàyè má sì ṣe wà láàyè fún ara wọn mọ́, bí kò ṣe fún ẹni tí ó kú nítorí wọn, tí ó sì ti jíǹde.

16 Nítorí náà láti ìṣinṣin yìí lọ, àwa kò mọ ẹnìkan nípa ti ara mọ́; bí àwa tilẹ̀ ti mọ Kírísítì nípa ti ara, ṣùgbọ́n níṣinṣin yìí àwa kò mọ̀ ọ́n bẹ́ẹ̀ mọ́.

17 Nítorí náà bí ẹnìkan bá wà nínú Kírísítì, ó di ẹ̀dá titun: ohun àtijọ́ ti kọjá lọ; kíyèsí i, ohun titun ti dé.

18 Ohun gbogbo sì ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá, ẹni tí ó sì típaṣẹ̀ Jésù Kírísítì bá wa làjà sọ́dọ̀ ara rẹ̀, tí ó sì ti fi iṣẹ́ ìránṣẹ́ ìlàjà fún wa.

19 Èyí ni pé, Ọlọ́run wà nínú Kírísítì, ó ń bá aráyé làjà sọ́dọ̀ ara rẹ̀, kò sí ka ìrékọjá wọn sí wọn lọ́rùn; ó sì ti fi ọ̀rọ̀ ìlàjà lé wa lọ́wọ́.

20 Nítorí náà àwa ni ikọ̀ fún Kírísítì, bí ẹni pé Ọlọ́run ń ti ọ̀dọ̀ wa ṣìpẹ̀ fún yín: àwa ń bẹ̀ yín nípò Kírísítì, “Ẹ bá Ọlọ́run làjà,”

21 Nítorí ó tí fi í ṣe ẹ̀ṣẹ̀ nítorí wa, ẹni tí kò mọ ẹ̀ṣẹ̀kẹ́ṣẹ̀ rí: kí àwa lè di òdodo Ọlọ́run nínú rẹ̀.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13