1 Ṣùgbọ́n èmi Pọ́ọ̀lù fúnra mi fi inú tútù àti ìwà pẹ̀lẹ́ Kírísítì bẹ̀ yín, èmi ẹni ìrẹ̀lẹ̀ lójú yín nígbà tí mo wà láàárin yín, ṣùgbọ́n nígbà tí èmi kò sí, mo di ẹni ìgboyà sí yín.
2 Ṣùgbọ́n èmi bẹ̀ yín pé nígbà tí mo wà láàárin yín, kí èmi baà lè lo ìgboyà pẹ̀lú ìgbẹ́kẹ̀lé náà, eléyìí tí mo ti fọkàn sí láti fi dojúkọ àwọn kan, ti ń fúra sí wa bí ẹni tí ń rìn nípa ti ara.
3 Nítorí pé, bí àwa tilẹ̀ rìn nípa ti ara, ṣùgbọ́n àwa kò jagun nípa ti ara.
4 Nítorí ohun ìjà wa kì í ṣe ti ara, ṣùgbọ́n ó lágbára nínú Ọlọ́run láti wó ibi gíga palẹ̀.
5 Àwa ń sọ gbogbo èrò àti gbogbo ohun gíga ti ń gbe ara rẹ̀ ga sí ìmọ̀ Ọlọ́run, àwa sì ń di gbogbo èrò ní ìgbékùn wá sí ìtẹríba fún Kírísítì.