15 Àwa kò ṣògo rékọjá ààlà wa, èyí nì, lórí iṣẹ́ elòmiràn, ṣùgbọ́n àwa ní ìrètí pé, bí ìgbàgbọ́ yín ti ń dàgbà sí i, gẹ́gẹ́ bí ààlà wa, àwa ó dí gbígbéga lọ́dọ̀ yín sí i lọ́pọ̀lọpọ̀.
16 Kí a bà à lè wàásù ìyìn rere ní àwọn ìlú tí ń bẹ níwájú yín, kí a má sì ṣògo nínú ààlà ẹlòmíràn nípa ohun tí ó wà ní àrọ́wọ́tó.
17 “Ṣùgbọ́n jẹ́ kí ẹni tí ó bá ń ṣògo, kí ó máa ṣògo nínú Olúwa.”
18 Nítorí kì í ṣe ẹni tí ń yin ara rẹ̀ ni ó ní itẹ́wọ́gbà, bí kò ṣe ẹni tí Olúwa bá yìn.