4 Nítorí ohun ìjà wa kì í ṣe ti ara, ṣùgbọ́n ó lágbára nínú Ọlọ́run láti wó ibi gíga palẹ̀.
5 Àwa ń sọ gbogbo èrò àti gbogbo ohun gíga ti ń gbe ara rẹ̀ ga sí ìmọ̀ Ọlọ́run, àwa sì ń di gbogbo èrò ní ìgbékùn wá sí ìtẹríba fún Kírísítì.
6 Àwa sì ti murá tan láti jẹ gbogbo àìgbọ́ràn níyà, nígbà tí ìgbọ́ràn yín bá pé.
7 Ẹ̀yin sì ń wo nǹkan gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti fi hàn lóde. Bí ẹnikẹ́ni bá ní ìgboyà nínú ara rẹ̀, ti Kírísítì ni òun, kí ó tún rò lẹ́ẹ̀kan si pé, bí òun ti jẹ́ ti Kírísítì, gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni àwa pẹ̀lú jẹ́ ti Kírísítì.
8 Nítorí bí mo tilẹ̀ ń ṣògo bí ó ti wù mi nítorí agbára, tí Olúwa ti fifún wá fún mímú yn ìdàgbàsókè, dípò fífa yín subú, ojú kí yóò tì mí.
9 Kí ó má ṣe dàbí ẹni pé èmi ń fí ìwé kíkọ dẹ́rùbá yín.
10 Nítorí wọ́n wí pé, “Ìwé rẹ wúwo, wọn sì lágbára; ṣùgbọ́n ìrísí rẹ̀ jẹ aláìlera, ọ̀rọ̀ rẹ kò níláárí.”