2 Nítorí pé èmi ń jówu lórí i yín ní ti owú ẹni ìwà-bí-Ọlọ́run: nítorí tí mo ti fì yín fún ọkọ kan, kí èmi bà á lè mú yín wá bí wúndíá tí ó mọ́ sọ́dọ̀ Kírísítì.
3 Ṣùgbọ́n ẹ̀rù ń bà mí, kí ó má bà á jẹ́ pé, bí ejò ti tan Éfà jẹ́ nípaṣẹ̀ àrékérekè rẹ̀, a lè mú ọkàn yín sáko lọ kúrò nínú òtítọ́ yín àti ìfarajìn fún Kírísítì.
4 Nítorí bí ẹnìkan bá wá tí ó sì wàásù Jésù mìíràn, yàtọ̀ sí èyí tí a ti wàásù rí tàbí bí ẹ̀yin bá gba ẹ̀mí mìíràn, yàtọ̀ sí èyí tí ẹ ti gbà tàbí ìyìn rere mìíràn yàtọ̀ sí èyí tí ẹ ti gbà, tí ẹ sì ti yára tẹ́wọ́ gbà á.
5 Nítorí mo rò pé èmi kò rẹ̀yìn ní ohunkohun sí àwọn àgbà Àpósítélì.
6 Bí mo tilẹ̀ jẹ́ òpè nínú ọ̀rọ̀ sísọ, kì í ṣe nínú ìmọ̀; Ní ọ̀nàkọnà ni àwa ti fi èyí hàn dájúdájú fún yín nínú ohun gbogbo.
7 Tàbí ẹ̀ṣẹ̀ ni mo dá bí èmi ti ń rẹ ara mí sílẹ̀ kí a lè gbé yín ga, nítorí tí mo wàásù ìyìn rere Ọlọ́run fún un yín lọ́fẹ̀ẹ́.
8 Èmí ń ja ìjọ mìíràn ni olè nípa gbigba ìpèsè owó ki èmi bà á lè sìn yín.