24 Nígbà márùn-ún ni mo gba pàṣán ogójì dín kan lọ́wọ́ àwọn Júù.
25 Nígbà mẹ́ta ni a fi ọ̀gọ̀ lù mí, ẹ̀ẹ̀kanṣoṣo ni a sọ mí ní òkúta, ẹ̀ẹ̀mẹ́ta ni ọkọ̀ ojú omi mi rì, ọ̀sán kan àti òru kan ni mo wà nínú ibú.
26 Ní ìrìnàjò nígbákùúgbà, nínú ewu omi, nínú ewu àwọn ọlọ́ṣà, nínú ewu àwọn ará ìlú mi, nínú ewu àwọn aláìkọlà, nínú ewu ni ìlú, nínú ewu ní ihà, nínú ewu lójú òkun, nínú ewu láàárin àwọn èké arákùnrin.
27 Nínú làálàá àti ìrora, nínú ìṣọ́-òru nígbákùúgbà, nínú ebi àti òrùgbẹ, nínú ààwẹ̀ nígbákùúgbà, nínú òtútù àti ìhòòhò.
28 Pẹ̀lú nǹkan wọ̀nyí tí ó jẹ́ tí òde, ọ̀pọ̀ ni èyí tí ń wọ́ jọ tì mí lójoojúmọ́, àní àníyàn fún gbogbo ìjọ.
29 Ta ni ó ṣe àìlera, tí èmi kò ṣe àìlera? Tàbí a mú kọsẹ̀, tí ara mi kò gbiná?
30 Bí èmi yóò bá ṣògo, èmi ó kúkú máa ṣògo nípa àwọn nǹkan tí ó jẹ́ ti àìlera mi.