30 Bí èmi yóò bá ṣògo, èmi ó kúkú máa ṣògo nípa àwọn nǹkan tí ó jẹ́ ti àìlera mi.
31 Ọlọ́run àti Baba Olúwa wá Jésù Kírísítì, ẹni tí ó jẹ́ olùbùkún jùlọ láéláé mọ̀ pé èmi kò ṣèké.
32 Ní Dámásíkù, baálẹ̀ tí ó wà lábẹ́ ọba Árétà fí ẹgbẹ́ ogun ká ìlú àwọn ara Dámásíkù mọ́, ó ń fẹ́ mi láti mú:
33 Láti ojú fèrèsé nínú agbọ̀n ni a sì ti sọ̀ mí kalẹ̀ lẹ́yìn odi, tí mo sì bọ́ lọ́wọ́ rẹ̀.