6 Bí mo tilẹ̀ jẹ́ òpè nínú ọ̀rọ̀ sísọ, kì í ṣe nínú ìmọ̀; Ní ọ̀nàkọnà ni àwa ti fi èyí hàn dájúdájú fún yín nínú ohun gbogbo.
7 Tàbí ẹ̀ṣẹ̀ ni mo dá bí èmi ti ń rẹ ara mí sílẹ̀ kí a lè gbé yín ga, nítorí tí mo wàásù ìyìn rere Ọlọ́run fún un yín lọ́fẹ̀ẹ́.
8 Èmí ń ja ìjọ mìíràn ni olè nípa gbigba ìpèsè owó ki èmi bà á lè sìn yín.
9 Nígbà tí mo sì wà pẹ̀lú yín, tí mo sì ṣe aláìní, èmi kò dẹ́rù pa ẹnikẹ́ni: nítorí ohun tí mo ṣe aláìní ni àwọn ará tí ó ti Makedóníà wá ti mú wá. Bẹ́ẹ̀ ni nínú ohun gbogbo mo pa ara mi mọ́ láti má ṣe jẹ́ ẹrù fún yín, èmi yóò sì pa ara mi mọ́ bẹ́ẹ̀.
10 Ó jẹ́ òtítọ́, Kírísítì tí ń bẹ nínú mi pé kò sí ẹni tí ó lè dá mi lẹ́kun ìṣògo yìí ni gbogbo ẹkùn Ákáyà.
11 Nítorí kín ni? Nítorí èmi kò fẹ́ràn yín ni bí? Ọlọ́run mọ̀.
12 Ṣùgbọ́n ohun ti mo ń ṣe ni èmi yóò sì máa ṣe, kí èmi lè mú ẹ̀fẹ̀ kúrò lọ́wọ́ àwọn tí wọn ń fẹ́ ṣẹ̀fẹ̀, pé nínú ohun tí wọ́n ṣògo, kí a lè rí wọn gẹ́gẹ́ bí àwa.