15 Èmi ó sì fi ayọ̀ ná ohun gbogbo tí mo bá ní, èmi ó sì ná ara mi fún ọkàn yín nítòótọ́; bí mo bá fẹ́ yín lọ́pọ̀lọpọ̀, ó há tọ́ kí ẹ̀yin kí ó fẹ́ràn mi díẹ̀ bí?
16 Ṣùgbọ́n ó dára bẹ́ẹ̀ tí èmi kò dẹ́rúbà yín: ṣùgbọ́n bí ọlọ́gbọ́n ènìyàn, èmi ń fí ọwọ́ ẹ̀rọ̀ mú yín.
17 Èmi há rẹ́ yín jẹ nípa ẹnikẹ́ni nínú àwọn tí mo rán sí yín bi?
18 Mo bẹ Títù, mo sì rán arákùnrin kan pẹ̀lú rẹ̀; Títù há rẹ́ yín jẹ bí? Nípa ẹ̀mi kan náà kọ́ àwa rìn bí? Ọ̀nà kan náà kọ́ àwa tọ̀ bí?
19 Ẹ̀yin há rò pé àwa ń sọ nǹkan wọ̀nyí láti gbèjà ara wa níwájú yín bí? Ní iwájú Ọlọ́run ni àwa ń ṣọrọ nínú Kírísítì; ṣùgbọ́n àwa ń ṣe ohun gbogbo, olùfẹ́ ọ̀wọ́n, láti gbé yín ró ni.
20 Nítorí ẹ̀rù ń bà mí pé, nígbà tí mo bá dé, èmi kì yóò bá yín gẹ́gẹ́ bí irú èyí tí mo fẹ́, àti pé ẹ̀yin yóò sì rí mi gẹ́gẹ́ bí irú èyí tí ẹ̀yin kò fẹ́: Kí ìjà, owú-jíjẹ, ìbínú, ìpínyà, ìsọ̀rọ̀-ẹni-lẹ́yìn, ìjírọ̀sọ̀, ìfẹẹ́gẹ̀, ìrúkèrúdò, má bà à wà.
21 Àti nígbà tí mo bá sì padà dé, kí Ọlọ́run mí má bà à rẹ̀ mí sílẹ̀ lójú yín, àti kí èmi má bà à sọkún nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn tí ó tí ṣẹ̀ náà tí kò sì ronúpìwàdà ẹ̀ṣẹ̀ ìwà èérí, àgbérè, àti wọ̀bìà tí wọ́n ti hù.