3 Níwọ̀n bí ẹ̀yin tí ń wá àmì Kírísítì ti ń sọ̀rọ̀ nínú mi, ẹni tí kì í ṣe àìlera sí yin, ṣùgbọ́n tí ó jẹ́ agbára nínú yín.
4 Nítorí pé a kàn án mọ́ àgbélébùú nípa àìlera, ṣùgbọ́n òun wà láàyè nípa agbára Ọlọ́run. Nítorí àwa pẹ̀lú já sí aláìlera nínú rẹ̀, ṣùgbọ́n àwa yóò wà láàyè pẹ̀lú rẹ̀ nípa agbára Ọlọ́run sí yín.
5 Ẹ máa wádìí ara yín, bí ẹ̀yin bá wà nínú ìgbàgbọ́; ẹ máa dán ara yín wò. Tàbí ẹ̀yin fúnra yín kò mọ ara yín pé Jésù Kírísítì wá nínú yín? Àfi bí ẹ̀yin bá jẹ́ àwọn tí a tanù.
6 Ṣùgbọ́n mo ní ìgbẹ́kẹ̀lé pé ẹ̀yin yóò mọ̀ pé, àwa kì í ṣe àwọn tí a tanù.
7 Ǹjẹ́ àwa ń gbàdúrà sí Ọlọ́run, kì í ṣe nítorí kí àwa lè farahàn bí àwọn ti ó tayọ̀, ṣùgbọ́n kí ẹ̀yin lè máa ṣe èyí tí ó dára bí àwa tilẹ̀ dàbí àwọn tí a tanù.
8 Nítorí àwa kò lè ṣe ohun kan lòdì sí òtítọ́, bí kò ṣe fún òtítọ́.
9 Nítorí àwa ń yọ̀, nígbà ti àwa jẹ́ aláìlera, tí ẹ̀yín sì jẹ́ alágbára; èyí ni àwa sì ń gbàdúrà fún pẹ̀lú, àní pípé yín.