5 Bí ẹnikẹ́ni bá fa ohun ìbànújẹ́ kì í ṣe èmi ni ó bà nínú jẹ́, bí kò ṣe ẹyin fúnra yín, níwọ̀n ìyówù kí ó jẹ́; n kò fẹ́ sọ ọ́ lọ́nà líle jù.
6 Ìyà náà tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ti fí jẹ́ irú ènìyàn bẹ́ẹ̀ tó fún un.
7 Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ̀yin ìbá kúkú dáríjì í, kí ẹ sí tù ú nínú ní gbogbo ọ̀nà, kí ìbànújẹ́ má bà á bo irú ènìyàn bẹ́ẹ̀ mọ́lẹ̀.
8 Nítorí náà mo bẹ̀ yín, ẹ fi ìdánilójú ìfẹ́ yín hàn sí Olúwa rẹ̀.
9 Ìdí tí mo ṣe kọ̀wé, kí èmi baà lè rí ẹ̀rí dìmú nípa ìgbọ́ràn yín nínú ohun gbogbo.
10 Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin bá dáríjín ẹnikẹ́ni, èmí fi jì pẹ̀lú. Èmi ti dárìjìn níwájú Kírítí nítorí yín.
11 Kí Sàtánì má baà rẹ́ wa jẹ. Nítorí àwa kò ṣe aláìmọ́ àrékérekè rẹ̀.