8 Nítorí náà, má ṣe tijú láti jẹ̀rìí nípa Olúwa wa, tàbí èmi òǹdè rẹ̀; ṣùgbọ́n kí ìwọ ṣe alábàápín nínú ìpọ́njú ìyìnrere nípa agbára Ọlọ́run,
9 ẹni ti ó gbà wá là, ti ó si pè wá sínú ìwà-mímọ́—kì í ṣe nípa iṣẹ́ tí a ṣe ṣùgbọ́n nípaṣẹ̀ ète àti oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀. Oore-ọ̀fẹ́ yìí ni a fi fún wa láti ìpìlẹ̀ ayérayé,
10 ṣùgbọ́n tí a fihàn níṣinṣinyìí nípa ìfarahàn Jésù Olùgbàlà wa, ẹni ti ó pa ikú run, tí ó sì mú ìyè àti àìkú wá sí ìmọ́lẹ̀ nípaṣẹ̀ ìyìnrere.
11 Fún ti ìyìnrere tí a yàn mi ṣe oníwàásù àti Àpósítélì àti olùkọ́.
12 Nítorí ìdí èyí ní èmi ṣe ń jìyà wọ̀nyí pẹ̀lú. Ṣùgbọ́n ojú kò tì mí: nítorí èmi mọ ẹni tí èmi gbàgbọ́, ó sì dá mi lójú pé, òun lè pa ohun ti mo fi lé e lọ́wọ́ mọ́ títí di ọjọ́ náà.
13 Ohun tí ó gbọ́ láti ọ̀dọ̀ mi, pa a mọ́ gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ ẹ̀kọ́ rere nínú ìgbàgbọ́ àti ìfẹ́ Kírísítì Jésù.
14 Pa ohun rere ti a ti fi lé ọ lọ́wọ́ mọ́ nípa Ẹ̀mí Mímọ́ ti ń gbé inú wa.