2 Àwọn ohun ti ìwọ ti gbọ́ lọ́dọ̀ mi níwájú ẹlẹ́rìí púpọ̀, àwọn náà ni kí ìwọ fi lé àwọn olóòótọ́ ènìyàn lọ́wọ́, àwọn ti yóò lè máa kọ́ àwọn ẹlòmíràn pẹ̀lú.
3 Ṣe alábàápín pẹ̀lú mi nínú ìpọ́njú, bí ọmọ-ogun rere Jésù Kírísítì.
4 Kò sí ẹni tí ń jagun ti ń fi ohun ayé yìí dí ara rẹ̀ lọ́wọ́, kí ó lè mú inú ẹni tí ó yàn ni ọmọ-ogun dùn.
5 Ní ọ̀nà kán náà, bí ẹnìkẹ́ni bá sì ń dije bí olùdíje, a kì í dé e ládé, bí kò ṣe bí ó bá parí rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìlànà
6 Àgbẹ̀ ti ó ń ṣe làálàá ni ó yẹ láti kọ́kọ́ mu nínú àwọn èso.
7 Ronú lórí ohun ti èmi ń sọ; nítorí Olúwa yóò fún ọ lóye nínú ohun gbogbo.
8 Rántí Jésù Kírísítì, ti ó jíǹde kúrò nínú òkú, láti inú irú-ọmọ Dáfídì gẹ́gẹ́ bí ìyìn rere mi.