3 Ṣe alábàápín pẹ̀lú mi nínú ìpọ́njú, bí ọmọ-ogun rere Jésù Kírísítì.
4 Kò sí ẹni tí ń jagun ti ń fi ohun ayé yìí dí ara rẹ̀ lọ́wọ́, kí ó lè mú inú ẹni tí ó yàn ni ọmọ-ogun dùn.
5 Ní ọ̀nà kán náà, bí ẹnìkẹ́ni bá sì ń dije bí olùdíje, a kì í dé e ládé, bí kò ṣe bí ó bá parí rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìlànà
6 Àgbẹ̀ ti ó ń ṣe làálàá ni ó yẹ láti kọ́kọ́ mu nínú àwọn èso.
7 Ronú lórí ohun ti èmi ń sọ; nítorí Olúwa yóò fún ọ lóye nínú ohun gbogbo.
8 Rántí Jésù Kírísítì, ti ó jíǹde kúrò nínú òkú, láti inú irú-ọmọ Dáfídì gẹ́gẹ́ bí ìyìn rere mi.
9 Nínú èyí tí èmi ń rí ìpọ́njú títí dé inú ìdè bí arúfin; ṣùgbọ́n a kò de ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.