9 Nínú èyí tí èmi ń rí ìpọ́njú títí dé inú ìdè bí arúfin; ṣùgbọ́n a kò de ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.
10 Nítorí náà mo ń faradà ohun gbogbo nítorí àwọn àyànfẹ́; kí àwọn náà pẹ̀lú lè ní ìgbàlà tí ń bẹ nínú Kírísítì Jésù pẹ̀lú ògo ayérayé.
11 Òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ náà:Bi àwa bá bá a kú,àwa yóò yè pẹ̀lú rẹ̀.
12 Bí àwa bá faradà,àwa ó sì bá a jọba:Bí àwa bá sẹ́ ẹ,òun náà yóò sì sẹ́ wa.
13 Bí àwa kò bá gbàgbọ́,òun dúró ni olóòótọ́:Nítorí òun kò lè sẹ ara rẹ̀.
14 Nǹkan wọ̀nyí ni ki ó máa rán wọn létí. Máa kìlọ̀ò fún wọn níwajú Olúwa pé, ki wọn ó yẹra kúrò nínú jíjiyàn ọ̀rọ̀ tí kò léèrè, bí kò ṣe ìparun fún àwọn tí ń gbọ́.
15 Ṣaápọn láti fi ara rẹ̀ hàn níwájú Ọlọ́run bi ẹni tí ó yege àti òṣìṣẹ́ tí kò níláti tijú, tí ó ń pin ọ̀rọ̀ òtítọ́ bí ó ti yẹ