10 Ṣùgbọ́n ìwọ ti mọ ẹ̀kọ́ mi, ìgbésí ayé mi, ìpinnu, ìgbàgbọ́, ìpamọ́ra, ìfẹ́-ni sùúrù.
11 Inúnibíni, ìyà; àwọn ohun tí ó dé bá mi ní Ańtíókù, Ní Ìkóníónì àti ní Lísítírà; àwọn inúnibíni tí mo faradà: Olúwa sì gbà mi kúrò nínú gbogbo wọn.
12 Nítòótọ́, gbogbo àwọn tí ó fẹ́ máa gbé ìgbé-ayé ìwà-bí-Ọlọ́run nínú Kírísítì Jésù yóò faradà inúnibíni
13 Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn búburú, àti àwọn ẹlẹ̀tàn yóò máa burú síwajú sí i, wọn ó máa tan-nijẹ, a ó sì máa tàn wọ́n jẹ.
14 Ṣùgbọ́n ìwọ dúró nínú nǹkan wọ̀nyí tí ìwọ ti kọ́, tí a sì ti jẹ́ kí ojú rẹ dá ṣáṣá sí, kí ìwọ sì mọ̀ ọ̀dọ̀ ẹni tí ìwọ gbé kọ́ wọn.
15 Àti pé láti ìgbà ọmọdé ni ìwọ ti mọ ìwé-Mímọ́, tí ó lè sọ ọ́ di ọlọ́gbọ́n sí ìgbàlà nípasẹ́ ìgbàgbọ́ nínú Kírísítì Jésù.
16 Gbogbo ìwé-Mímọ́ ni ó ní ìmísí Ọlọ́run tí ó sì ní èrè fún ẹ̀kọ́, fún ìbániwí, fún ìtọ́ni, fún ìkọ́ni tí ó wà nínú òdodo.