1 Pọ́ọ̀lù, Àpósítélì tí a rán kì í ṣe láti ọ̀dọ̀ ènìyàn wá, tàbí nípa ènìyàn, ṣùgbọ́n nípa Jésù Kírísítì àti Ọlọ́run Baba, ẹni tí ó jí i dìde kúrò nínú òkú.
2 Àti gbogbo àwọn arákùnrin tí ó wà pẹ̀lú mi,Sí àwọn ìjọ ní Gálátíà:
3 Oore-ọ̀fẹ́ sí yín àti àlàáfíà láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Baba wá àti Jésù Kírísítì Olúwa,
4 ẹni tí ó fí òun tìkararẹ̀ dípò ẹ̀ṣẹ̀ wa, kí ó lè gbà wá kúrò nínú ayé búburú ìsinsin yìí, gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ Ọlọ́run àti Baba wa,
5 ẹni tí ògo wà fún láé àti láéláé. Àmín.
6 Ẹnu yà mi nítorí tí pé ẹ tètè yapa kúrò lọ́dọ̀ ẹni tí ó pè yín sínú oore-ọ̀fẹ́ Kírísítì, sí ìyìn rere mìíràn:
7 èyí tí kì í ṣe ìyìn rere rárá. Ìdánilójú wà pé àwọn kan wà tí wọ́n ń sì yín lọ́nà, tí wọ́n sì ń fẹ́ yí ìyìn rere Kírísítì padà.