21 Lẹ́yìn náà mo sì wá sí agbègbè Síríà àti ti Kílíkáíà;
22 Mo sì jẹ́ ẹni tí a kò mọ̀ lójú fún àwọn ìjọ tí ó wà nínú Kírísítì ni Jùdíà:
23 Wọ́n kàn gbọ́ ìròyìn wí pé, “Ẹni tí ó tí ń ṣe inúnibíni sí wa rí, ní ìsinsìn yìí ti ń wàásù ìgbàgbọ́ náà tí ó ti gbìyànjú láti bàjẹ́ nígbà kan rí.”
24 Wọ́n sì yin Ọlọ́run lógo nítorí mi.