7 èyí tí kì í ṣe ìyìn rere rárá. Ìdánilójú wà pé àwọn kan wà tí wọ́n ń sì yín lọ́nà, tí wọ́n sì ń fẹ́ yí ìyìn rere Kírísítì padà.
8 Ṣùgbọ́n bí ó ṣe àwa ni tàbí ańgẹ́lì kan láti ọ̀run wá, ni ó bá wàásù ìyìn rere mìíràn fún yín ju èyí tí a tí wàásù rẹ̀ fún yín lọ, jẹ́ kí ó di ẹni ìfibú títí láéláé!
9 Bí àwa ti wí ṣáájú, bẹ́ẹ̀ ni mo sì tún wí nísinsinyìí pé: Bí ẹnìkan bá wàásù ìyìn rere mìíràn fún yín ju èyí tí ẹ̀yin tí gbà lọ, jẹ́ kí ó di ẹni ìfibú títí láéláé!
10 Ǹjẹ́ nísinsìnyìí ènìyàn ni èmi ń wá ojúrere rẹ̀ ní tàbí Ọlọ́run? Tàbí ènìyàn ni èmi ń fẹ́ láti wù bí? Bí èmi bá ń fẹ́ láti wu ènìyàn, èmi kò lè jẹ́ ìránṣẹ́ Kírísítì.
11 Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀, ará, pé ìyìn rere tí mo tí wàásù kì í ṣe láti ipa ènìyàn.
12 N kò gbà á lọ́wọ́ ènìyàn kankan, bẹ́ẹ̀ ni a kò fi kọ́ mi, ṣùgbọ́n mo gbà á nípa ìfihàn láti ọ̀dọ̀ Jésù Kírísítì.
13 Nítorí ẹ̀yin ti gbúrò ìwà-ayé mi nígbà àtijọ́ nínú ìsìn àwọn Júù, bí mo tí ṣe inúnibíni sí ìjọ ènìyàn Ọlọ́run rékọjá ààlà, tí mo sì lépa láti bà á jẹ́: