1 Nítorí náà, ẹ dúró ṣinṣin nínú òmìnira náà èyí tí Kírísítì fi sọ wá di òmìnira, kí ẹ má sì ṣe tún fi ọrùn bọ̀ àjàgà ẹrú mọ́.
2 Kíyèsí i, èmi Pọ́ọ̀lù ni ó wí fún yín pé, bí a bá kọ yín nílà, Kírísítì kì yóò lérè fún yín ní ohunkóhun.
3 Mo sì tún sọ fún olúkúlùkù ènìyàn tí a kọ ní ilà pé, ó di ajigbésè láti pa gbogbo òfin mọ́.
4 A ti yà yín kúrò lọ́dọ̀ Kírísítì, ẹ̀yin tí ń fẹ́ kí a dá yín láre nípa òfin; pé ẹ ti ṣubú kúrò nínú oore-ọ̀fẹ́.
5 Nítorí nípa Ẹ̀mí àwa ń fi ìgbàgbọ́ dúró de ìrètí òdodo.