8 Nítorí ẹni tí ó bá ń fúnrúngbìn sípa ti ara yóò ká ìdíbàjẹ́ ti ara ṣùgbọ́n ẹni tí ń fúnrúngbìn sípa ti ẹ̀mí yóò ti inú ẹ̀mí ká ìyè àìnípẹ̀kun.
9 Ẹ má sì jẹ́ kí àárẹ̀ ọkàn mú wa ní ṣíṣe rere, nítorí tí a ó kórè nígbà tí àkókò bá dé, bí a kò bá ṣe àárẹ̀.
10 Ǹjẹ́ bí a ti ń rí àkókò, ẹ jẹ́ kí a máa ṣoore fún gbogbo ènìyàn, àti pàápàá fún àwọn tí í ṣe ará ilé ìgbàgbọ́.
11 Ẹ wo bí mo ti fi ọwọ́ ara mi kọ̀wé gàdàgbà-gàdàgbà sí yín.
12 Iye àwọn tí ń fẹ́ ṣe àṣehàn ni ara wọn ń rọ yín láti kọlà; kìkì nítorí pé kí a má ba à ṣe inúnibíni sí wọn nítorí àgbélébùú Kírísítì.
13 Nítorí àwọn tí a kọ nílà pàápàá kò pa òfin mọ́, ṣùgbọ́n wọ́n ń fẹ́ mú yin kọlà, kí wọn lè máa ṣògo nínú ara yín.
14 Ṣùgbọ́n kí a má ṣe rí i pé èmi ń ṣògo, bí kò ṣe nínú àgbélébùú Jésù Kírísítì Olúwa wa, nípaṣẹ̀ ẹni tí a ti kan ayé mọ́ àgbélébùú fún mi, àti èmi fún ayé.