21 Ẹ̀yin baba, ẹ má ṣe mú àwọn ọmọ yín bínú, kí wọn má bà á rẹ̀wẹ̀sì.
22 Ẹ̀yin ẹrú, ẹ gbọ́ ti àwọn olówó yín nípa ti ara ní ohun gbogbo; kì í ṣe ní àrojú ṣe, bí àwọn aláṣehàn ènìyàn; ṣugbọ́n ní òtítọ́ inú, ní ìbẹ̀rù Ọlọ́run:
23 Ohunkóhun tí ẹ̀yin bá ń ṣe, ẹ máa fi tọkàntọkàn ṣe é fún Olúwa, kí í ṣe fún ènìyàn;
24 Kí ẹ mọ̀ pé lọ́wọ́ Olúwa ni ẹ̀yin ó gba èrè ogun: nítorí ẹ̀yin ń sìn Olúwa Kírísítì.
25 Ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe àìṣòdodo, yóò gbàá padà nítorí àìṣòdodo náà tí ó ti ṣe: kò sì sí ojúṣáájú.