11 Nígbà tí wọ́n kúrò níbẹ̀, wọ́n lọ gbógun ti ìlú Debiri. (Kiriati Seferi ni orúkọ tí wọ́n ń pe Debiri tẹ́lẹ̀.)
12 Kalebu ní ẹnikẹ́ni tí ó bá gbógun ti ìlú Kiriati Seferi tí ó sì ṣẹgun rẹ̀, ni òun óo fi Akisa, ọmọbinrin òun fún kí ó fi ṣe aya.
13 Otinieli, ọmọ Kenasi, àbúrò Kalebu, ṣẹgun ìlú náà, Kalebu bá fi Akisa, ọmọbinrin rẹ̀ fún un kí ó fi ṣe aya.
14 Nígbà tí Akisa dé ọ̀dọ̀ ọkọ rẹ̀, ọkọ rẹ̀ bẹ̀ ẹ́ pé kí ó tọrọ pápá ìdaran lọ́wọ́ baba rẹ̀. Ní ọjọ́ kan, Akisa lọ bá baba rẹ̀, bí ó ti ń sọ̀kalẹ̀ lórí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ni baba rẹ̀ bi í pé, “Kí lo fẹ́?”
15 Ó bá dá baba rẹ̀ lóhùn pé, “Ẹ̀bùn kan ni mo fẹ́ tọrọ. Ṣé o mọ̀ pé ilẹ̀ aṣálẹ̀ ni o fún mi; nítorí náà, fún mi ní orísun omi pẹlu rẹ̀.” Kalebu bá fún un ní àwọn orísun omi tí ó wà ní òkè ati ní ìsàlẹ̀.
16 Àwọn ọmọ ọmọ Keni, àna Mose, bá àwọn ọmọ Juda lọ láti Jẹriko, ìlú ọlọ́pẹ, sí inú aṣálẹ̀ Juda tí ó wà ní apá ìhà gúsù lẹ́bàá Aradi; wọ́n sì jọ ń gbé pọ̀ níbẹ̀.
17 Àwọn ọmọ Juda bá àwọn ọmọ Simeoni, arakunrin wọn, lọ sí ilẹ̀ àwọn ará Kenaani tí wọ́n ń gbé Sefati. Wọ́n gbógun tì wọ́n, wọ́n run wọ́n patapata, wọ́n sì sọ ìlú náà ní Horima.