Àwọn Adájọ́ 11:34-40 BM

34 Jẹfuta bá pada sí ilẹ̀ rẹ̀ nì Misipa, bí ó ti ń wọ̀lú bọ̀, ọmọ rẹ̀ obinrin wá pàdé rẹ̀ pẹlu ìlù ati ijó, ọmọbinrin yìí sì ni ọmọ kan ṣoṣo tí ó bí.

35 Bí ó ti rí i, ó fa aṣọ rẹ̀ ya ó ní, “Ha! Ọmọ mi, ìwọ ni o kó mi sinu ìbànújẹ́ yìí? Ó ṣe wá jẹ́ pé ọ̀rọ̀ tìrẹ ni yóo kó ìbànújẹ́ bá mi? Nítorí pé mo ti jẹ́jẹ̀ẹ́ níwájú OLUWA n kò sì gbọdọ̀ má mú un ṣẹ.”

36 Ọmọbinrin náà dá baba rẹ̀ lóhùn pé, “Baba mi, bí o bá ti jẹ́jẹ̀ẹ́ kan níwájú OLUWA, ṣe sí mi gẹ́gẹ́ bí ẹ̀jẹ́ rẹ níwọ̀n ìgbà tí OLUWA ti ràn ọ́ lọ́wọ́ láti gbẹ̀san lára àwọn ará Amoni, tí í ṣe ọ̀tá rẹ.”

37 Ó bá bẹ baba rẹ̀, ó ní, “Kinní kan ni mo fẹ́ kí o ṣe fún mi, fi mí sílẹ̀ fún oṣù meji, kí èmi ati àwọn ẹlẹgbẹ́ mi lọ sí orí òkè kí á máa káàkiri, kí á sì máa sọkún, nítorí pé mo níláti kú láì mọ ọkunrin.”

38 Baba rẹ̀ bá ní kí ó máa lọ fún oṣù meji. Òun ati àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ bá lọ sí orí òkè, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí sọkún, nítorí pé ó níláti kú, láì mọ ọkunrin.

39 Lẹ́yìn oṣù meji, ó pada sọ́dọ̀ baba rẹ̀, baba rẹ̀ sì ṣe bí ó ti jẹ́jẹ̀ẹ́ pé òun yóo ṣe, ọmọbinrin náà kò mọ ọkunrin rí rárá.Ó sì di àṣà ní ilẹ̀ Israẹli,

40 pé kí àwọn ọmọbinrin Israẹli máa lọ láti ṣọ̀fọ̀ ọmọbinrin Jẹfuta, ará Gileadi fún ọjọ́ mẹrin lọdọọdun.