Àwọn Adájọ́ 16:10-16 BM

10 Delila tún wí fún Samsoni pé, “Ò ń fi mí ṣe ẹlẹ́yà, o sì ń purọ́ fún mi. Jọ̀wọ́ sọ bí eniyan ṣe le dè ọ́ lókùn fún mi.”

11 Ó dá a lóhùn pé, “Tí wọ́n bá fi okùn titun, tí wọn kò tíì lò rí dè mí, yóo rẹ̀ mí, n óo sì dàbí àwọn ọkunrin yòókù.”

12 Delila bá mú okùn titun, ó fi dè é, ó sì wí fún un pé, “Samsoni, àwọn ará Filistia dé!” Àwọn tí wọ́n sápamọ́ sì wà ninu yàrá inú. Ṣugbọn Samsoni fa okùn náà já bí ẹni pé fọ́nrán òwú kan ni.

13 Delila tún wí fún Samsoni pé, “Sibẹsibẹ o ṣì tún ń fi mí ṣe ẹlẹ́yà, o tún ń purọ́ fún mi. Sọ fún mi bí eniyan ṣe lè gbé ọ dè.”Ó dá a lóhùn pé, “Bí o bá di ìdì irun meje tí ó wà lórí mi, mọ́ igi òfì, tí o sì dì í papọ̀, yóo rẹ̀ mi, n óo sì dàbí àwọn ọkunrin yòókù.”

14 Nítorí náà, nígbà tí ó sùn, Delila mú ìdì irun mejeeje tí ó wà lórí rẹ̀, ó lọ́ ọ mọ́ igi òfì, ó sì fi èèkàn kàn án mọ́lẹ̀, ó bá pè é, ó ní, “Samsoni! Àwọn Filistini dé.” Ṣugbọn nígbà tí ó jí láti ojú oorun rẹ̀, ó fa èèkàn ati igi òfì náà tu.

15 Delila tún sọ fún un pé, “Báwo ni o ṣe lè wí pé o nífẹ̀ẹ́ mí, nígbà tí ọkàn rẹ kò sí lọ́dọ̀ mi. O ti fi mí ṣe ẹlẹ́yà nígbà mẹta, o kò sì sọ àṣírí agbára ńlá rẹ fún mi.”

16 Nígbà tí Delila bẹ̀rẹ̀ sí yọ ọ́ lẹ́nu lemọ́lemọ́, tí ó sì ń rọ̀ ọ́ lojoojumọ, ọ̀rọ̀ náà sú Samsoni patapata.