4 Nígbà tí Mika kó owó náà fún ìyá rẹ̀, ìyá rẹ̀ mú igba owó fadaka ninu rẹ̀, ó kó o fún alágbẹ̀dẹ fadaka láti yọ́ ọ sórí ère náà, wọ́n sì gbé ère náà sí ilé Mika.
5 Mika ní ojúbọ kan fún ara rẹ̀, ó dá ẹ̀wù funfun kan, ó sì ṣe àwọn ère kéékèèké. Ó fi ọ̀kan ninu àwọn ọmọ rẹ̀ ṣe alufaa oriṣa rẹ̀.
6 Kò sí ọba ní ilẹ̀ Israẹli ní gbogbo àkókò náà, nítorí náà ohun tí ó bá tọ́ lójú olukuluku ni olukuluku ń ṣe.
7 Ọdọmọkunrin kan wà ní Juda, ará Bẹtilẹhẹmu, tí ó jẹ́ ọmọ Lefi láti inú ìdílé Juda, ó ń gbé ibẹ̀.
8 Ọdọmọkunrin náà kó kúrò ní Bẹtilẹhẹmu ní ilẹ̀ Juda, láti lọ máa gbé ibikíbi tí ó bá ti rí ààyè. Bí ó ti ń lọ, ó dé ilé Mika ní agbègbè olókè ti Efuraimu.
9 Mika bá bi í pé, “Níbo ni o ti ń bọ̀?”Ó dá a lóhùn pé, “Ọmọ Lefi, láti Bẹtilẹhẹmu ní ilẹ̀ Juda ni mí, ibi tí n óo máa gbé ni mò ń wá kiri.”
10 Mika bá sọ fún un pè, “Máa gbé ọ̀dọ̀ mi, kí o sì jẹ́ baba ati alufaa fún mi, n óo máa san owó fadaka mẹ́wàá fún ọ lọ́dún. N óo máa dáṣọ fún ọ, n óo sì máa bọ́ ọ.”