1 Debora ati Baraki ọmọ Abinoamu bá kọrin ní ọjọ́ náà pé:
2 Ẹ fi ìyìn fún OLUWA,nítorí pé, àwọn olórí ni wọ́n ṣiwaju ní Israẹli,àwọn eniyan sì fi tọkàntọkàn fa ara wọn kalẹ̀.
3 Ẹ gbọ́, ẹ̀yin ọba;ẹ tẹ́tí sílẹ̀ ẹ̀yin ìjòyè;OLUWA ni n óo kọrin sí,n óo kọrin dídùn sí OLUWA, Ọlọrun Israẹli.
4 OLUWA, nígbà tí o jáde lọ láti òkè Seiri,nígbà tí o jáde lọ láti agbègbè Edomu,ilẹ̀ mì tìtì,omi bẹ̀rẹ̀ sí bọ́,ọ̀wààrà òjò bẹ̀rẹ̀ sí rọ̀.
5 Àwọn òkè mì tìtì níwájú rẹ, OLUWA,àní, ní òkè Sinai níwájú OLUWA, Ọlọrun Israẹli.