15 Àwọn ìjòyè Isakari náà bá Debora wá,àwọn ọmọ Isakari jẹ́ olóòótọ́ sí Baraki,wọ́n sì dà tẹ̀lé e lẹ́yìn lọ sí àfonífojì.Àwọn ẹ̀yà Reubẹni ṣiyèméjì,ìmọ̀ wọn kò ṣọ̀kan láti wá.
16 Kí ló dé tí o fi dúró lẹ́yìn láàrin àwọn agbo aguntan?Tí o fi ń gbọ́ bí àwọn olùṣọ́-aguntan ti ń fọn fèrè fún àwọn aguntan wọn.Àwọn ẹ̀yà Reubẹni ṣiyèméjì,ìmọ̀ wọn kò ṣọ̀kan láti wá.
17 Àwọn ará Gileadi dúró ní ìlà oòrùn odò Jọdani,kí ló dé tí ẹ̀yà Dani fi dúró ní ìdí ọkọ̀ ojú omi?Àwọn ẹ̀yà Aṣeri jókòó létí òkun,wọ́n wà ní ẹsẹ̀ odò.
18 Àwọn ọmọ Sebuluni fi ẹ̀mí wọn wéwu dójú ikú,bẹ́ẹ̀ náà sì ni àwọn ọmọ Nafutali,wọ́n fi ẹ̀mí ara wọn wéwu ninu pápá, lójú ogun.
19 “Ní Taanaki lẹ́bàá odò Megidoàwọn ọba wá, wọ́n jagun,wọ́n bá àwọn ọba Kenaani jagun,ṣugbọn wọn kò rí ìkógun fadaka kó.
20 Láti ojú ọ̀run ni àwọn ìràwọ̀ ti ń jagun,àní láti ààyè wọn lójú ọ̀nà wọn,ni wọ́n ti bá Sisera jà.
21 Odò Kiṣoni kó wọn lọ,odò Kiṣoni, tí ó kún àkúnya.Máa yan lọ, ìwọ ọkàn mi, máa fi agbára yan lọ.