18 Àwọn ọmọ Sebuluni fi ẹ̀mí wọn wéwu dójú ikú,bẹ́ẹ̀ náà sì ni àwọn ọmọ Nafutali,wọ́n fi ẹ̀mí ara wọn wéwu ninu pápá, lójú ogun.
19 “Ní Taanaki lẹ́bàá odò Megidoàwọn ọba wá, wọ́n jagun,wọ́n bá àwọn ọba Kenaani jagun,ṣugbọn wọn kò rí ìkógun fadaka kó.
20 Láti ojú ọ̀run ni àwọn ìràwọ̀ ti ń jagun,àní láti ààyè wọn lójú ọ̀nà wọn,ni wọ́n ti bá Sisera jà.
21 Odò Kiṣoni kó wọn lọ,odò Kiṣoni, tí ó kún àkúnya.Máa yan lọ, ìwọ ọkàn mi, máa fi agbára yan lọ.
22 Àwọn ẹṣin sáré dé, pẹlu ariwo pátákò ẹsẹ̀ wọn,wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí fi ẹsẹ̀ kilẹ̀.”
23 Angẹli OLUWA ní, “Ìlú ègún ni ìlú Merosi,ẹni ègún burúkú sì ni àwọn olùgbé rẹ̀,nítorí pé wọ́n kọ̀, wọn kò wá ran OLUWA lọ́wọ́;wọn kò ran OLUWA lọ́wọ́ láti gbógun ti àwọn alágbára.”
24 Ẹni ibukun jùlọ ni Jaeli láàrin àwọn obinrin,Jaeli, aya Heberi, ọmọ Keni,ẹni ibukun jùlọ láàrin àwọn obinrin tí ń gbé inú àgọ́.