2 Ẹ fi ìyìn fún OLUWA,nítorí pé, àwọn olórí ni wọ́n ṣiwaju ní Israẹli,àwọn eniyan sì fi tọkàntọkàn fa ara wọn kalẹ̀.
3 Ẹ gbọ́, ẹ̀yin ọba;ẹ tẹ́tí sílẹ̀ ẹ̀yin ìjòyè;OLUWA ni n óo kọrin sí,n óo kọrin dídùn sí OLUWA, Ọlọrun Israẹli.
4 OLUWA, nígbà tí o jáde lọ láti òkè Seiri,nígbà tí o jáde lọ láti agbègbè Edomu,ilẹ̀ mì tìtì,omi bẹ̀rẹ̀ sí bọ́,ọ̀wààrà òjò bẹ̀rẹ̀ sí rọ̀.
5 Àwọn òkè mì tìtì níwájú rẹ, OLUWA,àní, ní òkè Sinai níwájú OLUWA, Ọlọrun Israẹli.
6 Ní ìgbà ayé Ṣamgari, ọmọ Anati,ati nígbà ayé Jaeli, ọ̀wọ́ èrò kò rin ilẹ̀ yìí mọ́,àwọn arìnrìnàjò sì ń gba ọ̀nà kọ̀rọ̀.
7 Gbogbo ìlú dá wáí ní Israẹli, ó dá,gbogbo ìlú di àkọ̀tì,títí tí ìwọ Debora fi dìde,bí ìyá, ní Israẹli.
8 Ní gbogbo ìgbà tí àwọn ọmọ Israẹli dá oriṣa titun,ogun bo gbogbo ẹnubodè.Ninu bí ọ̀kẹ́ meji (40,000) ọkunrin tí wọ́n wà ní Israẹli,ǹjẹ́ a rí ẹnikẹ́ni tí ó ní apata tabi ọ̀kọ̀?