23 Angẹli OLUWA ní, “Ìlú ègún ni ìlú Merosi,ẹni ègún burúkú sì ni àwọn olùgbé rẹ̀,nítorí pé wọ́n kọ̀, wọn kò wá ran OLUWA lọ́wọ́;wọn kò ran OLUWA lọ́wọ́ láti gbógun ti àwọn alágbára.”
24 Ẹni ibukun jùlọ ni Jaeli láàrin àwọn obinrin,Jaeli, aya Heberi, ọmọ Keni,ẹni ibukun jùlọ láàrin àwọn obinrin tí ń gbé inú àgọ́.
25 Omi ni Sisera bèèrè, wàrà ni Jaeli fún un,àwo tí wọ́n fi ń gbé oúnjẹ fún ọbani ó fi gbé e fún un mu.
26 Ó na ọwọ́ mú èèkàn àgọ́,ó na ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀, ó he òòlù àwọn alágbẹ̀dẹ,ó kan Sisera mọ́lẹ̀ lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo;ó fọ́ ọ lórí,ó lù ú ní ẹ̀bá etí,ó sì fọ́ yángá-yángá.
27 Sisera wó, ó ṣubú lulẹ̀,ó nà gbalaja lẹ́sẹ̀ Jaeli,ó wó lulẹ̀ lẹ́sẹ̀ rẹ̀, ó ṣubú lulẹ̀.Ibi tí ó wó sí, náà ni ó sì kú sí.
28 Ìyá Sisera ń yọjú láti ojú fèrèsé,ó bẹ̀rẹ̀ sí wo ọ̀nà láti ibi ihò fèrèsé.Ó ní, “Kí ló dé tí àwọn kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ fi pẹ́ tóbẹ́ẹ̀ kí wọ́n tó dé?Kí ló dé tí ó fi pẹ́ tóbẹ́ẹ̀ kí á tó gbúròó ẹsẹ̀ àwọn ẹṣintí wọ́n ń wọ́ kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀?”
29 Àwọn ọlọ́gbọ́n jùlọ ninu àwọn obinrin tí wọ́n wà lọ́dọ̀ rẹ̀ dá a lóhùn,òun náà sì ń wí fún ara rẹ̀ pé,