7 Gbogbo ìlú dá wáí ní Israẹli, ó dá,gbogbo ìlú di àkọ̀tì,títí tí ìwọ Debora fi dìde,bí ìyá, ní Israẹli.
8 Ní gbogbo ìgbà tí àwọn ọmọ Israẹli dá oriṣa titun,ogun bo gbogbo ẹnubodè.Ninu bí ọ̀kẹ́ meji (40,000) ọkunrin tí wọ́n wà ní Israẹli,ǹjẹ́ a rí ẹnikẹ́ni tí ó ní apata tabi ọ̀kọ̀?
9 Ọkàn mi lọ sọ́dọ̀ àwọn balogun Israẹli,tí wọ́n fi tọkàntọkàn fa ara wọn kalẹ̀ láàrin àwọn eniyan.Ẹ fi ìyìn fún OLUWA.
10 Ẹ máa fi ṣe ọ̀rọ̀ sọ,gbogbo ẹ̀yin tí ẹ̀ ń gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ funfun,gbogbo ẹ̀yin tí ẹ̀ ń jókòó lórí ẹní olówó iyebíye,ati gbogbo ẹ̀yin tí ẹ̀ ń fi ẹsẹ̀ rìn.
11 Ẹ tẹ́tí sí ohùn àwọn akọrin lẹ́bàá odò,ibẹ̀ ni wọ́n ti ń sọ̀rọ̀ nípa ìṣẹ́gun OLUWA,ọ̀rọ̀ ìṣẹ́gun àwọn eniyan rẹ̀ ní Israẹli.Àwọn eniyan OLUWA sì yan jáde láti ẹnubodè ìlú wọn.
12 Gbéra ńlẹ̀! Gbéra ńlẹ̀! Debora!Gbéra ńlẹ̀! Gbéra ńlẹ̀, kí o dárin!Dìde, Baraki, máa kó àwọn tí o kó lógun lọ,ìwọ ọmọ Abinoamu!
13 Àwọn akikanju yòókù bẹ̀rẹ̀ sí yan bọ̀,àwọn eniyan OLUWA náà sì ń wọ́ bọ̀,láti gbógun ti alágbára.