Ẹkún Jeremaya 1:5-11 BM

5 Àwọn ọ̀tá ilẹ̀ Juda ti borí rẹ̀, wọ́n ti wá di ọ̀gá rẹ̀,nítorí pé, OLUWA ń jẹ ẹ́ níyà fún ọpọlọpọ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀,àwọn ọ̀tá ti ti àwọn ọmọ rẹ̀ ṣáájú,wọ́n ti kó wọn nígbèkùn lọ.

6 Gbogbo ògo Jerusalẹmu ti fò lọ kúrò lára rẹ̀,àwọn olórí rẹ̀ dàbí àgbọ̀nríntí kò rí koríko tútù jẹ;agbára kò sí fún wọn mọ́,wọ́n ń sálọ níwájú àwọn tí ń lé wọn.

7 Ní ọjọ́ ìpọ́njú ati ìbànújẹ́,Jerusalẹmu ranti àwọn nǹkan iyebíye tí ó ní ní ìgbà àtijọ́.Nígbà tí àwọn eniyan rẹ̀ bọ́ sọ́wọ́ ọ̀tá,tí kò sì sí ẹni tí yóo ràn wọ́n lọ́wọ́.Àwọn ọ̀tá bẹ̀rẹ̀ sí yọ̀ ọ́,wọ́n sì ń fi ṣẹ̀sín nítorí ìṣubú rẹ̀.

8 Jerusalẹmu ti dẹ́ṣẹ̀ burúkú,nítorí náà ó ti di eléèérí.Àwọn tí wọn ń bu ọlá fún un tẹ́lẹ̀ ti ń kẹ́gàn rẹ̀,nítorí pé wọ́n ti rí ìhòòhò rẹ̀.Òun pàápàá ń kérora, ó sì fi ojú pamọ́.

9 Ìwà èérí rẹ̀ hàn níbi ìṣẹ́tí aṣọ rẹ̀,kò sì bìkítà fún ìparun tí ń bọ̀.Nítorí náà ni ìṣubú rẹ̀ fi pọ̀, tí kò sì fi ní olùtùnú.Ó ké pe OLUWA pé kí ó ṣíjú wo ìnira òun,nítorí pé ọ̀tá ti borí rẹ̀.

10 Ọ̀tá ti tọwọ́ bọ ilé ìṣúra rẹ̀,wọ́n sì ti kó gbogbo nǹkan iyebíye inú rẹ̀ lọ;ó ń wo àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn,tí wọn ń wọ ibi mímọ́ rẹ̀.Àwọn tí ó pàṣẹ péwọn kò gbọdọ̀ dé àwùjọ àwọn eniyan rẹ̀.

11 Gbogbo àwọn eniyan rẹ̀ ń kérorabí wọ́n ti ń wá oúnjẹ;wọ́n ń fi ìṣúra wọn ṣe pàṣípààrọ̀ fún oúnjẹkí wọ́n baà lè lágbára.Jerusalẹmu ń sunkún pé,“Bojúwò mí, OLUWA,nítorí pé mo di ẹni ẹ̀gàn.”