2 Ẹ wo àwọn ọdọmọkunrin Sioni,àwọn ọmọ tí wọn níye lórí bí ojúlówó wúrà,tí a wá ń ṣe bí ìkòkò amọ̀;àní, bí ìkòkò amọ̀ lásánlàsàn.
3 Àwọn ajáko a máa fún àwọn ọmọ wọn lọ́mú.Ṣugbọn àwọn eniyan mi ti di ìkà,bí ògòǹgò inú aṣálẹ̀.
4 Ahọ́n ọmọ ọmú lẹ̀ mọ́ òkè ẹnu rẹ̀ nítorí òùngbẹ.Àwọn ọmọde ń tọrọ oúnjẹ,ṣugbọn kò sí ẹni tí ó fún wọn.
5 Àwọn tí wọn tí ń jẹ oúnjẹ àdídùndi ẹni tí ń ṣa ilẹ̀ jẹ kiri ní ìgboro.Àwọn tí wọn tí ń fi aṣọ àlàárì boradi ẹni tí ń sùn lórí òkítì eérú.
6 Ìjìyà àwọn eniyan mi pọ̀ ju ti àwọn ará Sodomu lọ,Sodomu tí ó parun lójijì,láìjẹ́ pé eniyan fi ọwọ́ kàn án.
7 Àwọn olórí wọn kò ní àléébù kankan,Ọwọ́ wọn mọ́, inú wọn funfun nini,wọ́n dára ju egbin lọ,ẹwà wọn sì dàbí ẹwà iyùn.
8 Ṣugbọn nisinsinyii, ojú wọn dúdú ju èédú lọ,kò sí ẹni tí ó dá wọn mọ̀ láàrin ìgboro,awọ ara wọn ti hunjọ lórí egungun wọn,wọ́n wá gbẹ bí igi.