Ẹsita 1:16-22 BM

16 Memkani bá dáhùn níwájú ọba ati àwọn ìjòyè pé, “Kì í ṣe ọba nìkan ni Faṣiti kò kà sí, bíkòṣe gbogbo àwọn ìjòyè ati gbogbo àwọn tí wọ́n wà ní agbègbè ìjọba Ahasu-erusi ọba.

17 Nǹkan tí Faṣiti ṣe yìí yóo di mímọ̀ fún àwọn obinrin, àwọn náà yóo sì máa fi ojú tẹmbẹlu àwọn ọkọ wọn. Wọn yóo máa wí pé, ‘Ọba ṣá ti ranṣẹ sí ayaba pé kí ó wá siwaju òun rí, tí ó kọ̀, tí kò lọ.’

18 Láti òní lọ, àwọn obinrin, pàápàá àwọn obinrin Pasia ati ti Media, tí wọ́n ti gbọ́ ohun tí Ayaba ṣe yóo máa fi ṣe ọ̀rọ̀ sọ sí àwọn ìjòyè. Èyí yóo sì mú kí aifinipeni ati ibinu pọ̀ sí i.

19 Nítorí náà bí ó bá wu ọba, kí ọba pàṣẹ, kí á sì kọ ọ́ sinu ìwé òfin Pasia ati ti Media, tí ẹnikẹ́ni kò lè yipada, pé Faṣiti kò gbọdọ̀ dé iwájú ọba mọ́, kí ọba sì fi ipò rẹ̀ fún ẹlòmíràn tí ó sàn jù ú lọ.

20 Nígbà tí a bá kéde òfin yìí jákèjádò agbègbè rẹ, àwọn obinrin yóo máa bu ọlá fún àwọn ọkọ wọn; ọkọ wọn kì báà jẹ́ talaka tabi olówó.”

21 Inú ọba ati àwọn ìjòyè dùn sí ìmọ̀ràn yìí, nítorí náà ọba ṣe bí Memkani ti sọ.

22 Ó fi ìwé ranṣẹ sí gbogbo ilẹ̀ ìjọba rẹ̀, ati sí gbogbo agbègbè ati àwọn ẹ̀yà, ní èdè kaluku wọn, pé kí olukuluku ọkunrin máa jẹ́ olórí ninu ilé rẹ̀.