10 Ọba bọ́ òrùka àṣẹ tí ó wà ní ọwọ́ rẹ̀, ó fún Hamani, ọmọ Hamedata, ará Agagi, ọ̀tá àwọn Juu.
11 Ọba sọ fún un pé, “Má wulẹ̀ san owó kankan, àwọn eniyan náà wà ní ìkáwọ́ rẹ, lọ ṣe wọ́n bí o bá ti fẹ́.”
12 Ní ọjọ́ kẹtala, oṣù kinni, Hamani pe àwọn akọ̀wé ọba jọ, wọ́n sì kọ gbogbo àṣẹ tí Hamani pa sinu ìwé. Wọ́n fi ìwé náà ranṣẹ sí àwọn gomina agbègbè ati àwọn olórí àwọn eniyan ati sí àwọn agbègbè kọ̀ọ̀kan ati ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan ní èdè wọn. Wọ́n kọ ìwé náà ní orúkọ ọba, wọ́n sì fi òrùka ọba ṣe èdìdì rẹ̀.
13 Wọ́n fi àwọn ìwé náà rán àwọn òjíṣẹ́ sí gbogbo agbègbè ọba pé kí wọ́n pa gbogbo àwọn Juu run, ati kékeré ati àgbà, ati obinrin ati ọmọde ní ọjọ́ kan náà, tíí ṣe ọjọ́ kẹtala oṣù kejila oṣù Adari, kí wọ́n sì kó gbogbo ohun ìní wọn.
14 Wọ́n níláti sọ ohun tí ó wà ninu ìwé náà di òfin ní gbogbo ìgbèríko, kí wọ́n sì sọ fún gbogbo eniyan, kí wọ́n lè múra sílẹ̀ de ọjọ́ náà.
15 Wọ́n pa àṣẹ náà ní Susa tíí ṣe olú-ìlú, àwọn òjíṣẹ́ sì yára mú un lọ gẹ́gẹ́ bí àṣẹ ọba. Lẹ́yìn náà, Hamani ati ọba jókòó láti mu ọtí, ṣugbọn gbogbo ìlú Susa wà ninu ìdààmú.