Ẹsita 3:4-10 BM

4 Ojoojumọ ni wọ́n ń kìlọ̀ fún un, ṣugbọn kò gbọ́. Nítorí náà, wọ́n lọ sọ fún Hamani, wọ́n fẹ́ mọ̀ bóyá ohun tí Modekai sọ ni yóo ṣẹ, nítorí ó sọ fún wọn pé Juu ni òun.

5 Nígbà tí Hamani rí i pé Modekai kọ̀, kò foríbalẹ̀ fún òun, inú bí i pupọ.

6 Nígbà tí ó mọ̀ pé Juu ni, ó kà á sí ohun kékeré láti pa Modekai nìkan, nítorí náà, ó pinnu láti pa gbogbo àwọn Juu tí wọ́n jẹ́ eniyan Modekai run, ní gbogbo ilẹ̀ ìjọba Ahasu-erusi.

7 Ní ọdún kejila ìjọba Ahasu-erusi, Hamani pinnu láti yan ọjọ́ tí ó wọ̀, nítorí náà, ní oṣù kinni tíí ṣe oṣù Nisani, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ṣẹ́ gègé tí wọn ń pè ní Purimu, níwájú Hamani láti ọjọ́ dé ọjọ́ ati láti oṣù dé oṣù, títí dé oṣù kejila tíí ṣe oṣù Adari.

8 Nígbà náà ni Hamani lọ bá Ahasu-erusi ọba, ó sọ fún un pé, “Àwọn eniyan kan wà tí wọ́n fọ́n káàkiri ààrin àwọn eniyan ati ní gbogbo agbègbè ìjọba rẹ; òfin wọn kò bá ti gbogbo eniyan mu, wọn kò sì pa àṣẹ ọba mọ́. Kò dára kí o gbà wọ́n láàyè ninu ìjọba rẹ.

9 Bí ó bá dùn mọ́ Kabiyesi ninu, jẹ́ kí àṣẹ kan jáde lọ láti pa wọ́n run. N óo sì gbé ẹgbaarun (10,000) ìwọ̀n talẹnti fadaka fún àwọn tí a bá fi iṣẹ́ náà rán, kí wọ́n gbé e sí ilé ìṣúra ọba.”

10 Ọba bọ́ òrùka àṣẹ tí ó wà ní ọwọ́ rẹ̀, ó fún Hamani, ọmọ Hamedata, ará Agagi, ọ̀tá àwọn Juu.