4 Ọba bèèrè pé, “Ta ló wà ninu àgbàlá?” Àkókò náà ni Hamani wọ inú àgbàlá ààfin ọba, láti bá ọba sọ̀rọ̀ láti so Modekai rọ̀ sórí igi tí ó rì mọ́lẹ̀.
5 Àwọn iranṣẹ ọba dá a lóhùn pé, “Hamani wà níbẹ̀ tí ó ń duro ní àgbàlá.” Ọba sì wí pé, “Ẹ jẹ́ kí ó wọlé.”
6 Bí Hamani tí ń wọlé ni ọba bi í pé, “Kí ló yẹ kí á ṣe fún ẹni tí inú ọba dùn sí?”Hamani rò ó ninu ara rẹ̀ pé, ta ni ọba ìbá tún dá lọ́lá bíkòṣe òun.
7 Nítorí náà, ó dá ọba lóhùn pé, “Báyìí ni ó ṣe yẹ kí á dá ẹni tí inú ọba dùn sí lọ́lá:
8 kí wọ́n mú aṣọ ìgúnwà ọba, tí ọba ti wọ̀ rí, ati ẹṣin tí ó ti gùn rí, kí wọ́n sì fi adé ọba dé ẹni náà lórí,
9 kí wọ́n kó wọn fún ọ̀kan ninu àwọn ìjòyè ọba tí ó ga jùlọ, kí ó fi ṣe ẹni náà lọ́ṣọ̀ọ́, kí ó gbé e gun ẹṣin, kí ó sì fà á káàkiri gbogbo ìlú, kí ó máa kéde pé, ‘Ẹ wo ohun tí ọba ṣe fún ẹni tí inú rẹ̀ dùn sí láti dá a lọ́lá.’ ”
10 Ọba bá sọ fún Hamani pé, “Yára lọ mú aṣọ ìgúnwà, ati ẹṣin náà, kí o sì ṣe bí o ti wí sí Modekai, Juu, tí ó máa ń jókòó sí ẹnu ọ̀nà ààfin.”