1 Ní ọjọ́ náà gan-an ni ọba Ahasu-erusi fún Ẹsita Ayaba ní ilé Hamani, ọ̀tá àwọn Juu. Ẹsita wá sọ fún ọba pé eniyan òun ni Modekai. Láti ìgbà náà ni ọba sì ti mú Modekai wá siwaju rẹ̀.
2 Ọba mú òrùka tí ó gbà lọ́wọ́ Hamani, ó fi bọ Modekai lọ́wọ́. Ẹsita sì fi Modekai ṣe olórí ilé Hamani.
3 Ẹsita tún bẹ ọba, ó wólẹ̀ ní ẹsẹ̀ rẹ̀, ó sì bẹ̀ ẹ́ pẹlu omijé, pé kí ọba yí ète burúkú tí Hamani, ará Agagi, pa láti run àwọn Juu pada.
4 Nígbà náà ni ọba na ọ̀pá àṣẹ wúrà sí Ẹsita.