5 Ẹ jí lójú oorun, ẹ̀yin ọ̀mùtí,ẹ sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn,gbogbo ẹ̀yin tí ẹ̀ ń mu waini,nítorí waini tuntun tí a já gbà kúrò lẹ́nu yín.
6 Orílẹ̀-èdè kan ti dojú kọ ilẹ̀ mi,wọ́n lágbára, wọ́n pọ̀, wọn kò sì lóǹkà;eyín wọn dàbí ti kinniun.Ọ̀gàn wọn sì dàbí ti abo kinniun.
7 Wọ́n ti run ọgbà àjàrà mi,wọ́n ti já àwọn ẹ̀ka igi ọ̀pọ̀tọ́ mi,wọ́n ti bó gbogbo èèpo ara rẹ̀,wọ́n ti wó o lulẹ̀,àwọn ẹ̀ka rẹ̀ sì ti di funfun.
8 Ẹ sọkún bí ọmọge tí ó fi aṣọ ọ̀fọ̀ bora,nítorí ikú àfẹ́sọ́nà ìgbà èwe rẹ̀.
9 A ti dáwọ́ ẹbọ ohun jíjẹ ati ti ohun mímu dúró ní ilé OLUWA,àwọn alufaa tíí ṣe iranṣẹ OLUWA ń ṣọ̀fọ̀.
10 Ilẹ̀ ti gbẹ, ó ń ṣọ̀fọ̀,nítorí a ti run ọkà, àjàrà ti tán, epo olifi sì ń tán lọ.
11 Ẹ banújẹ́, ẹ̀yin àgbẹ̀,ẹ sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn ẹ̀yin tí ẹ̀ ń tọ́jú ọgbà àjàrà,nítorí ọkà alikama ati ọkà baali,ati nítorí pé ohun ọ̀gbìn ti ṣègbé.