Joẹli 2 BM

Ọ̀wọ́ Eṣú, gẹ́gẹ́ bí Àmì Ìkéde Ọjọ́ OLUWA

1 Ẹ fun fèrè ní Sioni,ẹ kéde ìdágìrì lórí òkè mímọ́ mi.Kí gbogbo àwọn tí wọn ń gbé ilẹ̀ náà wárìrì,nítorí ọjọ́ OLUWA ń bọ̀, ó sì ti dé tán.

2 Yóo jẹ́ ọjọ́ òkùnkùn ati ìbànújẹ́,ọjọ́ ìkùukùu ati òkùnkùn biribiri.Àwọn ọmọ ogun yóo bo gbogbo òkè ńlá,bí ìgbà tí òkùnkùn bá ń ṣú bọ̀.Irú rẹ̀ kò ṣẹlẹ̀ rí ní ìgbà àtijọ́,bẹ́ẹ̀ ni irú rẹ̀ kò sì tún ní ṣẹlẹ̀ mọ́ títí lae.

3 Iná ń jó àjórun níwájú wọn,ahọ́n iná ń yọ lálá lẹ́yìn wọn.Ilẹ̀ náà dàbí ọgbà Edẹni níwájú wọn,ṣugbọn lẹ́yìn wọn, ó dàbí aṣálẹ̀ tí ó ti di ahoro,kò sì sí ohun tí yóo bọ́ lọ́wọ́ wọn.

4 Ìrísí wọn dàbí ìrísí ẹṣin,wọ́n sì ń sáré bí ẹṣin tí ń lọ ojú ogun.

5 Ìró wọn dàbí ìró kẹ̀kẹ́ ogun,wọ́n ń bẹ́ lórí àwọn òkè ńlá.Ìró wọn dàbí ìró iná tí ń jó pápá,bí ìgbà tí àwọn alágbára ọmọ ogun múra fún ogun.

6 Ìdààmú bá àwọn orílẹ̀-èdè tí ó bá ti fojú kàn wọ́n,gbogbo ọkàn á rẹ̀wẹ̀sì.

7 Wọ́n ń sáré bí akọni,wọ́n ń fo ògiri bí ọmọ ogun.Wọ́n tò lọ́wọ̀ọ̀wọ́,ẹnikẹ́ni kò sì yà kúrò ní ọ̀nà tirẹ̀.

8 Wọn kò fi ara gbún ara wọn,olukuluku ń lọ ní ọ̀nà tirẹ̀;wọ́n kọlu àwọn nǹkan ààbò láìní ìdádúró.

9 Wọ́n ń gun odi ìlú,wọ́n ń sáré lórí odi.Wọ́n ń gun orí ilé wọlé,wọ́n gba ojú fèrèsé bẹ́ sinu ọ̀dẹ̀dẹ̀ bí olè.

10 Ilẹ̀ ń mì tìtì níwájú wọn,ọ̀run sì ń wárìrì,oòrùn, òṣùpá ati àwọn ìràwọ̀ ṣókùnkùn.

11 OLUWA sọ̀rọ̀ níwájú àwọn ọmọ ogun rẹ̀,nítorí àwọn ọmọ ogun rẹ̀ pọ̀ lọpọlọpọ,alágbára ni ẹni tí ń mú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣẹ.Ọjọ́ ńlá ati ọjọ́ ẹ̀rù ni ọjọ́ OLUWA!Ta ló lè faradà á?

Ìpè fún Ìrònúpìwàdà

12 OLUWA ní, “Ẹ yipada sí mi tọkàntọkàn nisinsinyii,pẹlu ààwẹ̀, ẹkún ati ìkẹ́dùn,

13 Ìrònúpìwàdà tòótọ́ ni mò ń fẹ́,kì í ṣe pé kí ẹ fa aṣọ yín ya nìkan.”Ẹ yipada sí OLUWA Ọlọrun yín,nítorí olóore-ọ̀fẹ́ ati aláàánú ni.Kì í yára bínú,Ó kún fún ìfẹ́ tí kì í yẹ̀,a sì máa dárí ẹ̀ṣẹ̀ ji eniyan.

14 Ó ṣeéṣe kí Ọlọrun ṣàánú, kí ó yí ibinu rẹ̀ pada,kí ó sì tú ibukun rẹ̀ sílẹ̀,kí ẹ lè rú ẹbọ ohun jíjẹ ati ẹbọ ohun mímu fún OLUWA Ọlọrun yín.

15 Ẹ fọn fèrè ní òkè Sioni,ẹ kéde ààwẹ̀ kí ẹ sì pe àpéjọ.

16 Ẹ pe gbogbo eniyan jọ,kí ẹ sì ya ìjọ eniyan sí mímọ́.Ẹ pe àwọn àgbààgbà jọ,ẹ kó àwọn ọmọde ati àwọn ọmọ ọwọ́ jọ.Kí ọkọ iyawo jáde láti inú yàrá rẹ̀,kí iyawo àṣẹ̀ṣẹ̀gbé náà jáde ninu yàrá rẹ̀.

17 Kí àwọn alufaa, àwọn iranṣẹ Ọlọrun, sọkún láàrin ẹnu ọ̀nà àbáwọlé ati pẹpẹ ìrúbọ.Kí wọ́n wí pé “OLUWA, dá àwọn eniyan rẹ sí,má sì sọ ilẹ̀ rẹ di ohun ẹ̀gàn ati ohun ẹ̀sín láàrin àwọn orílẹ̀-èdè yòókù.Má jẹ́ kí àwọn eniyan láàrin àwọn orílẹ̀-èdè yòókù bèèrè pé,‘Níbo ni Ọlọrun wọn wà?’ ”

Ọlọrun Yóo Dá Ìbísí Pada sórí Ilẹ̀ náà

18 Nígbà náà ni ara bẹ̀rẹ̀ sí ta OLUWA nítorí ilẹ̀ rẹ̀,ó sì ṣàánú fún àwọn eniyan rẹ̀.

19 OLUWA dá àwọn eniyan rẹ̀ lóhùn pé,“Wò ó! N óo fun yín ní ọkà, waini ati òróró,ẹ óo ní ànítẹ́rùn.N kò ní sọ yín di ẹni ẹ̀gàn láàrin àwọn orílẹ̀-èdè yòókù mọ́.

20 N óo kó àwọn eṣú láti ìhà àríwá jìnnà kúrò lọ́dọ̀ yín,n óo lé wọn lọ sinu aṣálẹ̀ níbi tí kò sí nǹkankan.N óo lé àwọn tí wọ́n wà níwájú lọ sí inú òkun, ní apá ìlà oòrùn,n óo sì lé àwọn tí wọ́n wà lẹ́yìn lọ sí inú òkun, ní apá ìwọ̀ oòrùn.Òkú wọn yóo máa rùn;n óo pa wọ́n run nítorí ibi ńlá tí wọ́n ṣe.

21 Má bẹ̀rù, ìwọ ilẹ̀,jẹ́ kí inú rẹ máa dùn,kí o sì máa yọ̀,nítorí OLUWA ti ṣe nǹkan ńlá.

22 Ẹ má bẹ̀rù, ẹ̀yin ẹranko inú igbó,nítorí ewéko gbogbo ni ó tutù,igi gbogbo ti so èso,igi ọ̀pọ̀tọ́ ati ọgbà àjàrà sì ti so jìnwìnnì.

23 “Ẹ máa yọ̀, ẹ̀yin ará Sioni,kí inú yín máa dùn ninu OLUWA Ọlọrun yín;nítorí ó ti da yín láre, ó ti fun yín ní àkọ́rọ̀ òjò,ó ti rọ ọpọlọpọ òjò fun yín:ati òjò àkọ́rọ̀, ati àrọ̀kẹ́yìn òjò, gẹ́gẹ́ bí ìṣe rẹ̀.

24 Gbogbo ibi ìpakà ni yóo kún fún ọkà,ìkòkò waini ati ti òróró yín yóo kún àkúnwọ́sílẹ̀.

25 Gbogbo ohun tí ẹ pàdánùní àwọn ọdún tí àwọn ọmọ ogun mi tí mo rán si yín ti jẹ oko yín;ati èyí tí eṣú wẹẹrẹ jẹ, ati èyí tí eṣú ńláńlá jẹ,gbogbo rẹ̀ ni n óo dá pada fun yín.

26 Ẹ óo jẹ oúnjẹ àjẹyó ati àjẹtẹ́rùn,ẹ óo sì yin orúkọ OLUWA Ọlọrun yín,tí ó ṣe ohun ìyanu ńlá fun yín,ojú kò sì ní ti àwọn eniyan mi mọ́ lae.

27 Ẹ óo mọ̀ pé mo wà láàrin Israẹli;ati pé èmi OLUWA ni Ọlọrun yín,kò sí ẹlòmíràn lẹ́yìn mi mọ́.Ojú kò sì ní ti àwọn eniyan mi mọ́ lae.

Ọjọ́ OLUWA

28 “Lẹ́yìn náà, nígbà tí ó bá yá,n óo tú ẹ̀mí mi jáde sára gbogbo eniyan,àwọn ọmọkunrin ati àwọn ọmọbinrinyín yóo máa sọ àsọtẹ́lẹ̀,àwọn àgbààgbà yín yóo máa lá àlá,àwọn ọdọmọkunrin yín yóo sì máa ríran.

29 Bákan náà, nígbà tí àkókò bá tó,n óo tú ẹ̀mí mi jáde sára àwọn iranṣẹkunrin ati àwọn iranṣẹbinrin yín.

30 “Ìtàjẹ̀sílẹ̀ yóo pọ̀,n óo sì fi iná, ati òpó èéfín sí ojú ọ̀run,ati sórí ilẹ̀ ayé;yóo jẹ́ ìkìlọ̀ fun yín.

31 Oòrùn yóo ṣókùnkùn,òṣùpá yóo pọ́n rẹ̀bẹ̀tẹ̀ bí ẹ̀jẹ̀,kí ọjọ́ OLUWA tí ó lẹ́rù tó dé.

32 Ṣugbọn gbogbo àwọn tí wọ́n bá ké pe orúkọ OLUWA ni a óo gbàlà.Àwọn kan yóo sá àsálà ní òkè Sioni,ní Jerusalẹmu, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti sọ,àwọn tí OLUWA pè yóo sì wà lára àwọn tí wọn yóo sá àsálà.

orí

1 2 3