1 “Wò ó! Nígbà tó bá yá, tí mo bá dá ire Juda ati ti Jerusalẹmu pada,
2 n óo kó gbogbo orílẹ̀-èdè jọ sí àfonífojì Jehoṣafati,n óo sì dá wọn lẹ́jọ́ níbẹ̀;nítorí ohun tí wọ́n ti ṣe sí Israẹli, àwọn eniyan mi.Wọ́n ti fọ́n wọn káàkiri sí ààrin àwọn orílẹ̀-èdè,wọ́n sì ti pín ilẹ̀ mi.
3 Wọ́n ti ṣẹ́ gègé lórí àwọn eniyan mi,wọ́n ti ta àwọn ọmọkunrin wọn,wọ́n fi owó wọn san owó aṣẹ́wó,wọ́n sì ta àwọn ọmọbinrin wọn,wọ́n fi owó wọn ra ọtí waini.
4 “Kí ni mo fi ṣe yín rí, ẹ̀yin ilẹ̀ Tire, ati ilẹ̀ Sidoni ati gbogbo agbègbè Filistini? Ṣé ẹ̀ ń gbẹ̀san nǹkankan lára mi ni? Bí ó bá jẹ́ pé ẹ̀ ń gbẹ̀san nǹkankan ni, n óo da ẹ̀san tí ẹ̀ ń gbà le yín lórí kíákíá;
5 nítorí ẹ ti kó fadaka ati wúrà ati àwọn ìṣúra mi olówó iyebíye lọ sí ilé oriṣa yín.
6 Ẹ ta àwọn ará Juda ati àwọn ará Jerusalẹmu fún àwọn ará Giriki, ẹ kó wọn jìnnà réré sí ilẹ̀ wọn.
7 Ṣugbọn nisinsinyii, n óo gbé wọn dìde níbi tí ẹ tà wọ́n sí, n óo sì gbẹ̀san ìwà yín lára ẹ̀yin alára.
8 N óo ta àwọn ọmọ yín ọkunrin ati àwọn ọmọ yín obinrin lẹ́rú fún àwọn ará Juda. Wọn yóo sì tà wọ́n fún àwọn ará Sabea, orílẹ̀-èdè tí ó jìnnà réré; nítorí OLUWA ni ó sọ bẹ́ẹ̀.”
9 Ẹ kéde èyí láàrin gbogbo orílẹ̀-èdè.Ẹ múra ogun,ẹ rú àwọn akọni sókè.Kí gbogbo àwọn ọmọ ogun súnmọ́ tòsí,ogun yá!
10 Ẹ fi irin ọkọ́ yín rọ idà,ẹ fi dòjé yín rọ ọ̀kọ̀,kí àwọn tí wọn kò lágbára wí pé, “Ọmọ ogun ni mí.”
11 Ẹ yára, ẹ wá,gbogbo ẹ̀yin orílẹ̀-èdè tí ẹ wà ní àyíká,ẹ parapọ̀ níbẹ̀.Rán àwọn ọmọ ogun rẹ wá, OLUWA.
12 Jẹ́ kí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè dìde,kí wọ́n wá sí àfonífojì Jehoṣafati,nítorí níbẹ̀ ni n óo ti ṣe ìdájọ́ gbogbo orílẹ̀-èdè tí ó wà ní àyíká.
13 Ẹ ti dòjé bọ oko, nítorí àkókò ìkórè ti tó,ẹ lọ fún ọtí waini nítorí ibi ìfúntí ti kún.Ìkòkò ọtí ti kún àkúnwọ́sílẹ̀,nítorí ìkà wọ́n pọ̀.
14 Ogunlọ́gọ̀ wà ní àfonífojì ìdájọ́,nítorí ọjọ́ OLUWA kù sí dẹ̀dẹ̀ níbẹ̀.
15 Oòrùn ati òṣùpá ti ṣókùnkùn,àwọn ìràwọ̀ kò sì tan ìmọ́lẹ̀ mọ́.
16 OLUWA kígbe láti Sioni,ó sọ̀rọ̀ láti Jerusalẹmu;ọ̀run ati ayé mì tìtì,ṣugbọn OLUWA ni ààbò fún àwọn eniyan rẹ̀,òun ni ibi ààbò fún Israẹli.
17 “Israẹli, o óo mọ̀ pé èmi ni OLUWA, Ọlọrun rẹ,èmi ni mò ń gbé Sioni, òkè mímọ́ mi.Jerusalẹmu yóo di ìlú mímọ́,àwọn àjèjì kò sì ní ṣẹgun mọ́.
18 “Nígbà náà, àwọn òkè ńlá yóo kún fún èso àjàrà,agbo mààlúù yóo sì pọ̀ lórí àwọn òkè kéékèèké.Gbogbo àwọn odò Juda yóo kún fún omi.Odò kan yóo bẹ̀rẹ̀ sí ṣàn láti ilé OLUWA,yóo sì bomi rin àfonífojì Ṣitimu.
19 “Ijipti yóo di aṣálẹ̀;Edomu yóo sì di ẹgàn,nítorí ìwà ipá tí wọ́n hù sí àwọn ará Juda,nítorí wọ́n ti pa àwọn aláìṣẹ̀ ní ilẹ̀ wọn.
20 Ṣugbọn àwọn eniyan yóo máa gbé ilẹ̀ Juda títí lae,wọn óo sì máa gbé ìlú Jerusalẹmu láti ìrandíran.
21 N óo gbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ àwọn tí ẹ pa, n kò sì ní dá ẹlẹ́bi sí,nítorí èmi OLUWA ni mò ń gbé Sioni.”