Joẹli 2:13-19 BM

13 Ìrònúpìwàdà tòótọ́ ni mò ń fẹ́,kì í ṣe pé kí ẹ fa aṣọ yín ya nìkan.”Ẹ yipada sí OLUWA Ọlọrun yín,nítorí olóore-ọ̀fẹ́ ati aláàánú ni.Kì í yára bínú,Ó kún fún ìfẹ́ tí kì í yẹ̀,a sì máa dárí ẹ̀ṣẹ̀ ji eniyan.

14 Ó ṣeéṣe kí Ọlọrun ṣàánú, kí ó yí ibinu rẹ̀ pada,kí ó sì tú ibukun rẹ̀ sílẹ̀,kí ẹ lè rú ẹbọ ohun jíjẹ ati ẹbọ ohun mímu fún OLUWA Ọlọrun yín.

15 Ẹ fọn fèrè ní òkè Sioni,ẹ kéde ààwẹ̀ kí ẹ sì pe àpéjọ.

16 Ẹ pe gbogbo eniyan jọ,kí ẹ sì ya ìjọ eniyan sí mímọ́.Ẹ pe àwọn àgbààgbà jọ,ẹ kó àwọn ọmọde ati àwọn ọmọ ọwọ́ jọ.Kí ọkọ iyawo jáde láti inú yàrá rẹ̀,kí iyawo àṣẹ̀ṣẹ̀gbé náà jáde ninu yàrá rẹ̀.

17 Kí àwọn alufaa, àwọn iranṣẹ Ọlọrun, sọkún láàrin ẹnu ọ̀nà àbáwọlé ati pẹpẹ ìrúbọ.Kí wọ́n wí pé “OLUWA, dá àwọn eniyan rẹ sí,má sì sọ ilẹ̀ rẹ di ohun ẹ̀gàn ati ohun ẹ̀sín láàrin àwọn orílẹ̀-èdè yòókù.Má jẹ́ kí àwọn eniyan láàrin àwọn orílẹ̀-èdè yòókù bèèrè pé,‘Níbo ni Ọlọrun wọn wà?’ ”

18 Nígbà náà ni ara bẹ̀rẹ̀ sí ta OLUWA nítorí ilẹ̀ rẹ̀,ó sì ṣàánú fún àwọn eniyan rẹ̀.

19 OLUWA dá àwọn eniyan rẹ̀ lóhùn pé,“Wò ó! N óo fun yín ní ọkà, waini ati òróró,ẹ óo ní ànítẹ́rùn.N kò ní sọ yín di ẹni ẹ̀gàn láàrin àwọn orílẹ̀-èdè yòókù mọ́.