Rutu 1 BM

Elimeleki ati Ìdílé Rẹ̀ Lọ láti Máa Gbé ní Ilẹ̀ Moabu

1 Ní àkókò tí àwọn adájọ́ ń ṣe olórí ní ilẹ̀ Israẹli, ìyàn ńlá kan mú ní ilẹ̀ náà. Ọkunrin kan wà, ará Bẹtilẹhẹmu, ní ilẹ̀ Juda, òun ati aya rẹ̀, ati àwọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin mejeeji; wọ́n lọ ń gbé ilẹ̀ Moabu.

2 Orúkọ ọkunrin náà ni Elimeleki, aya rẹ̀ ń jẹ́ Naomi, àwọn ọmọkunrin rẹ̀ sì ń jẹ́ Maloni ati Kilioni. Wọ́n kó kúrò ní Efurata ti Bẹtilẹhẹmu, ní ilẹ̀ Juda, wọ́n kó lọ sí ilẹ̀ àwọn ará Moabu, wọ́n sì ń gbé ibẹ̀.

3 Nígbà tí ó yá, Elimeleki kú, ó bá ku Naomi, opó rẹ̀, ati àwọn ọmọkunrin rẹ̀ mejeeji.

4 Àwọn ọmọ rẹ̀ mejeeji fẹ́ aya láàrin àwọn ọmọ Moabu, Iyawo ẹnikinni ń jẹ́ Opa, ti ẹnìkejì sì ń jẹ́ Rutu. Lẹ́yìn nǹkan bíi ọdún mẹ́wàá tí wọ́n ti jọ ń gbé ilẹ̀ Moabu,

5 Maloni ati Kilioni náà kú, Naomi sì ṣe bẹ́ẹ̀ ṣòfò àwọn ọmọ rẹ̀ mejeeji ati ọkọ rẹ̀.

Naomi ati Rutu Pada sí Bẹtilẹhẹmu

6 Naomi ati àwọn opó àwọn ọmọ rẹ̀ mejeeji jáde kúrò ní ilẹ̀ Moabu, wọ́n ń pada lọ sí ilẹ̀ Juda, nítorí ó gbọ́ pé OLUWA ti ṣàánú fún àwọn eniyan rẹ̀ ní ilẹ̀ Juda, ati pé wọ́n ti ń rí oúnjẹ jẹ.

7 Òun ati àwọn opó àwọn ọmọ rẹ̀ bá gbéra láti ilẹ̀ Moabu, wọ́n ń lọ sí ilẹ̀ Juda.

8 Bí wọ́n ti ń lọ, Naomi yíjú pada sí àwọn mejeeji, ó ní, “Ẹ̀yin mejeeji, ẹ pada sí ilé ìyá yín. Kí OLUWA ṣàánú fun yín, bí ẹ ti ṣàánú fún èmi ati àwọn òkú ọ̀run.

9 Kí OLUWA ṣe ilé ọkọ tí ẹnìkọ̀ọ̀kan yín bá tún ní, ní ilé rẹ̀.” Ó bá kí wọn, ó fi ẹnu kò wọ́n lẹ́nu, ó dágbére fún wọn, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí sọkún.

10 Wọ́n dáhùn, wọ́n ní, “Rárá o, a óo bá ọ pada lọ sọ́dọ̀ àwọn eniyan rẹ.”

11 Naomi dá wọn lóhùn, ó ní, “Ẹ pada, ẹ̀yin ọmọ mi. Kí ló dé tí ẹ fẹ́ bá mi lọ? Ọmọ wo ló tún kù ní ara mi tí n óo ṣẹ̀ṣẹ̀ bí, tí yóo ṣú yín lópó?

12 Ẹ pada, ẹ̀yin ọmọ mi, ẹ máa bá tiyín lọ. Ogbó ti dé sí mi, n kò tún lè ní ọkọ mọ́. Bí mo bá tilẹ̀ wí pé mo ní ìrètí, tí mo sì ní ọkọ ní alẹ́ òní, tí mo sì bí àwọn ọmọkunrin,

13 ṣé ẹ óo dúró títí wọn óo fi dàgbà ni, àbí ẹ óo sọ pé ẹ kò ní ní ọkọ mọ́? Kò ṣeéṣe, ẹ̀yin ọmọ mi. Ó dùn mí fun yín pé OLUWA ti bá mi jà.”

14 Wọ́n bá tún bẹ̀rẹ̀ sí sọkún. Nígbà tí ó yá, Opa fi ẹnu ko ìyá ọkọ rẹ̀ lẹ́nu, ó sì dágbére fún un; ṣugbọn Rutu kò kúrò lọ́dọ̀ ìyakọ rẹ̀.

15 Naomi bá sọ fún Rutu, ó ní, “Ṣé o rí i pé arabinrin rẹ ti pada sọ́dọ̀ àwọn eniyan rẹ̀ ati àwọn oriṣa rẹ̀, ìwọ náà pada, kí ẹ jọ máa lọ.”

16 Ṣugbọn Rutu dáhùn, ó ní, “Má pàrọwà fún mi rárá, pé kí n fi ọ́ sílẹ̀, tabi pé kí n pada lẹ́yìn rẹ; nítorí pé ibi tí o bá ń lọ, ni èmi náà yóo lọ; ibi tí o bá ń gbé ni èmi náà yóo máa gbé; àwọn eniyan rẹ ni yóo máa jẹ́ eniyan mi, Ọlọrun rẹ ni yóo sì jẹ́ Ọlọrun mi.

17 Ibi tí o bá kú sí, ni èmi náà yóo kú sí; níbẹ̀ ni wọn yóo sì sin mí sí pẹlu. Ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí ọ yìí, kí OLUWA jẹ́ kí ohun tí ó burú jù bẹ́ẹ̀ lọ bá mi, bí mo bá jẹ́ kí ohunkohun yà mí kúrò lẹ́yìn rẹ, ìbáà tilẹ̀ jẹ́ ikú.”

18 Nígbà tí Naomi rí i pé Rutu ti pinnu ninu ọkàn rẹ̀ láti bá òun lọ, kò sọ ohunkohun mọ́.

19 Àwọn mejeeji bá bẹ̀rẹ̀ sí lọ títí wọ́n fi dé Bẹtilẹhẹmu. Nígbà tí wọ́n wọ Bẹtilẹhẹmu, gbogbo ìlú mì tìtì nítorí wọn. Àwọn obinrin bá bẹ̀rẹ̀ sí bèèrè pé, “Ṣé Naomi nìyí?”

20 Naomi bá dá wọn lóhùn, ó ní, “Ẹ má pè mí ní Naomi mọ́, Mara ni kí ẹ máa pè mí nítorí pé Olodumare ti jẹ́ kí ayé korò fún mi.

21 Mo jáde lọ ní kíkún, ṣugbọn OLUWA ti mú mi pada ní ọwọ́ òfo, kí ló dé tí ẹ fi ń pè mí ní Naomi, nígbà tí OLUWA fúnra rẹ̀ ti dá mi lẹ́bi, tí Olodumare sì ti mú ìpọ́njú bá mi?”

22 Báyìí ni Naomi ati Rutu, ará Moabu, aya ọmọ rẹ̀, ṣe pada dé láti ilẹ̀ àwọn ará Moabu. Ní àkókò ìbẹ̀rẹ̀ ìkórè ọkà baali ni wọ́n dé sí Bẹtilẹhẹmu.

orí

1 2 3 4