Rutu 3 BM

Rutu rí Ọkọ Fẹ́

1 Lẹ́yìn náà, Naomi pe Rutu, ó ní, “Ọmọ mi, ó tó àkókò láti wá ọkọ fún ọ, kí ó lè dára fún ọ.

2 Ṣé o ranti pé ìbátan wa ni Boasi, tí o wà pẹlu àwọn ọmọbinrin rẹ̀? Wò ó, yóo lọ fẹ́ ọkà baali ní ibi ìpakà rẹ̀ lálẹ́ òní.

3 Nítorí náà, lọ wẹ̀, kí o sì fi nǹkan pa ara. Wọ aṣọ rẹ tí ó dára jùlọ, kí o sì lọ sí ibi ìpakà rẹ̀, ṣugbọn má jẹ́ kí ó mọ̀ pé o wà níbẹ̀ títí di ìgbà tí ó bá jẹ tí ó sì mu tán.

4 Nígbà tí ó bá fẹ́ sùn, ṣe akiyesi ibi tí ó sùn sí dáradára, lẹ́yìn náà, lọ ṣí aṣọ kúrò ní ẹsẹ̀ rẹ̀, kí o sì sùn tì í, lẹ́yìn náà, yóo sọ ohun tí o óo ṣe fún ọ.”

5 Rutu bá dá Naomi lóhùn, ó ní, “Gbogbo ohun tí o sọ fún mi ni n óo ṣe.”

6 Rutu bá lọ sí ibi ìpakà, ó ṣe bí ìyá ọkọ rẹ̀ ti sọ fún un.

7 Nígbà tí Boasi jẹ, tí ó mu tán, tí inú rẹ̀ sì dùn, ó lọ sùn lẹ́yìn òkítì ọkà Baali tí wọ́n ti pa. Rutu bá rọra lọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, ó ṣí aṣọ kúrò ní ẹsẹ̀ rẹ̀, ó sì sùn tì í.

8 Nígbà tí ó di ọ̀gànjọ́ òru, Boasi tají lójijì, bí ó ti yí ara pada, ó rí i pé obinrin kan sùn ní ibi ẹsẹ̀ òun.

9 Ó bá bèèrè, pé, “Ìwọ ta ni?”Rutu dáhùn, ó ní, “Èmi Rutu, iranṣẹbinrin rẹ ni. Da aṣọ rẹ bo èmi iranṣẹbinrin rẹ, nítorí pé ìwọ ni ìbátan tí ó súnmọ́ ọkọ mi jùlọ.”

10 Boasi bá dáhùn, ó ní, “OLUWA yóo bukun fún ọ, ọmọ mi, oore tí o ṣe ní ìkẹyìn yìí tóbi ju ti àkọ́kọ́ lọ; nítorí pé o kò wá àwọn ọdọmọkunrin lọ, kì báà jẹ́ olówó tabi talaka.

11 Má bẹ̀rù, ọmọ mi, gbogbo ohun tí o bèèrè ni n óo ṣe fún ọ, nítorí pé gbogbo àwọn ọkunrin ẹlẹgbẹ́ mi ní ilẹ̀ yìí ni wọ́n mọ̀ pé obinrin gidi ni ọ́.

12 Òtítọ́ ni mo jẹ́ ìbátan tí ó súnmọ́ ọkọ rẹ, ṣugbọn ẹnìkan wà tí ó tún súnmọ́ ọn jù mí lọ.

13 Sùn títí di òwúrọ̀, nígbà tí ó bá di òwúrọ̀ bí ó bá tẹ́ ẹ lọ́rùn láti ṣú ọ lópó gẹ́gẹ́ bí ẹ̀tọ́ rẹ̀, ó dára, jẹ́ kí ó ṣe bẹ́ẹ̀. Ṣugbọn bí kò bá fẹ́ ṣe ẹ̀tọ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìbátan, bí OLUWA ti wà láàyè, n óo ṣe ẹ̀tọ́, gẹ́gẹ́ bí ìbátan tí ó súnmọ́ ọn. Sùn títí di òwúrọ̀.”

14 Rutu bá sùn lẹ́bàá ẹsẹ̀ rẹ̀ títí di òwúrọ̀ ọjọ́ keji, ṣugbọn ó tètè dìde ní àfẹ̀mọ́jú, kí eniyan tó lè dá eniyan mọ̀. Boasi bá kìlọ̀ fún un pé, “Ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ mọ̀ pé o wá sí ibi ìpakà.”

15 Boasi sọ fún un pe kí ó tẹ́ aṣọ ìlékè rẹ̀, kí ó sì fi ọwọ́ mú un, Rutu náà sì ṣe bẹ́ẹ̀. Boasi wọn ìwọ̀n ọkà Baali mẹfa sinu aṣọ náà, ó dì í, ó gbé e ru Rutu, Rutu sì pada sí ilé.

16 Nígbà tí ó dé ọ̀dọ̀ ìyá ọkọ rẹ̀, ìyá ọkọ rẹ̀ bi í pé, “Báwo ni ibẹ̀ ti rí, ọmọ mi?”Rutu bá sọ gbogbo ohun tí ọkunrin náà ṣe fún un.

17 Ó ní, “Ìwọ̀n ọkà Baali mẹfa ni ó dì fún mi, nítorí ó sọ pé n kò gbọdọ̀ pada sí ọ̀dọ̀ ìyá ọkọ mi ní ọwọ́ òfo.”

18 Naomi bá dáhùn, ó ní, “Fara balẹ̀ ọmọ mi, títí tí o óo fi gbọ́ bí ọ̀rọ̀ náà yóo ti yọrí sí; nítorí pé ara ọkunrin yìí kò ní balẹ̀ títí tí yóo fi yanjú ọ̀rọ̀ náà lónìí.”

orí

1 2 3 4